Ikọ Amọtẹkun ti mu awọn ọrẹ meji to pa Isaac sinu oko, ti wọn tun gbe ọkada rẹ sa lọ l’Ekiti

Dada Ajikanje

Pako bii maaluu to rọbẹ lawọn ọmọkunrin meji kan, Ayọ Lawal ati Jimọ Ojo, ti ikọ Amọtẹkun mu nipinlẹ Ekiti pe wọn pa ọmọkunrin ọlọkada kan, Isaac, wọn si sinku rẹ sinu oko kan ni Itapagbaji to wa nijọba ibilẹ Ikọle, nipinlẹ Ekiti.

Gẹgẹ bi olori awọn Amọtẹkun nipinlẹ Ekiti, Ọgagunfẹyinti Joe Kọmọlafẹ, ṣe sọ, niṣe ni awọn meji naa gbimọ-pọ pẹlu awọn mẹta mi-in, ti wọn si fọgbọn tan ọmọkunrin naa pe ko gbe awọn ni ọkada lati ilu Ikọle lọ si oko kan ni Itapagbaji Ekiti. Ibẹ ni ọmọkunrin yii n gbe wọn lọ ti wọn fi doju ija kọ ọ lori ọkada, ti wọn si pa a. Lẹyin ti wọn pa a tan ni wọn sin oku rẹ sinu oko ọkan ninu wọn, Ayọ Lawal, ti wọn si gbe ọkada rẹ sa lọ.

Nigba ti wọn n ṣafihan awọn afurasi naa, ọkan ninu wọn, Lawal, sọ pe Abdullahi lo ni ki awọn pa ọmọkunrin naa, pe tawọn ba pa a, oun le ri ọkada rẹ ta ti oun ba gbe e lọ si Okenne, nipinlẹ Kogi. Tawọn ba si ta a tan, awọn aa pin owo naa laarin ara awọn ti awọn maa fi ra eebu iṣu ti awọn maa gbin sinu oko awọn lọdun to n bọ.

Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Sunday Abutu, sọ pe ọwọ awọn ti tẹ meji ninu awọn ọdaran naa, wọn si ti jẹwọ pe loootọ lawọn huwa ipaniyan ọhun. O ni awọn ṣi n wa Abdullahi ati ọmọkunrin kan ti wọn n pe ni Wonder ti wọn gbe okada Isaac lọ si Ọkenne, nipinlẹ Kogi, lati ta a.

Alukoro ni awọn kan ti wọn ta awọn lolobo lo jẹ ki awọn ri Ayọ ati ẹni keji rẹ mu ninu oṣu kọkanla, ọdun yii, latigba naa lawọn si ti n wa awọn yooku ti wọn jọ ṣịṣẹ ibi naa.

Leave a Reply