Iku Adegoke: Igbẹjọ Adedoyin pari, ọkunrin naa ko ri ẹlẹrii kankan pe

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Onidaajọ Adepele Ojo to n ṣe ẹjọ ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan Dokita Rahmon Adedoyin atawọn oṣiṣẹ ile-itura rẹ mẹfa, ti kede pe igbẹjọ ti pari lori ọrọ naa.

Adedoyin atawọn oṣiṣẹ rẹ ni wọn n jẹjọ lori iku to pa akẹkọọ Fasiti Ifẹ kan, Timothy Adegoke, sinu otẹẹli Hilton, to wa niluu Ileefẹ, ninu oṣu Kọkanla, ọdun 2021.

Lẹyin ti wọn kọkọ pari igbẹjọ lọdun to kọja ni agbẹjọro ti awọn mọlẹbi Adegoke gba, Fẹmi Falana, SAN rọ ileẹjọ pe awọn fẹẹ fi kun awọn ẹsun ti wọn fi kan awọn olujẹjọ.

Nigba naa ni Falana fi ẹsun ipaniyan kun ẹsun ti wọn fi kan Dokita Adedoyin, agbẹjọro rẹ, Barisita Kehinde Ẹlẹja, SAN, sọ fun ileẹjọ pe yoo pe awọn ẹlẹrii meji.

Latari pe wọn ko ri ẹlẹrii ti Adedoyin fẹẹ pe mu wa si kootu nijoko igbẹjọ to kọja ni wọn ṣe sun igbẹjọ siwaju di ọjọ keji, oṣu Keji, ọdun 2023.

Ṣugbọn ni kootu ni agbẹjọro Adedoyin tun ti sọ pe gbogbo igbiyanju awọn lati gbe awọn ẹlẹrii mejeeji to ni wa si kootu lo ja si pabo.

Ẹlẹja ṣalaye pe awọn gbiyanju lati gbe Dokita Benedict Agpo ti Nigeria Police Forensic Science Laboratory lati Force CID Annex, Alagbon, nipinlẹ Eko, ati Inspẹkitọ Victor Ekpenyong wa, ṣugbọn ko ṣee ṣe.

O ni wakati mẹrinlelogun sẹyin ni Ekpenyong ṣẹṣẹ sọ pe oun ni iṣẹ nita. Nitori naa, o ni pẹlu bi awọn ko ṣe lanfaani lati gbe awọn ẹlẹrii naa wa, ki kootu pari igbẹjọ olujẹjọ akọkọ to jẹ Adedoyin.

Bakan naa ni agbẹjọro awọn olujẹjọ yooku sọ pe awọn naa fara mọ ọn ki igbẹjọ pari.

Nitori naa, Onidaajọ Adepele Ojo kede ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹta, ọdun yii, gẹgẹ bii ọjọ ti awọn agbẹjọro fun gbogbo awọn olujẹjọ yoo mu akọsilẹ awijare wọn (Final written addresses) wọn wa.

Leave a Reply