Faith Adebọla, Eko
Latari iku ọkan ninu awọn akẹkọọ ileewe wọn, mẹrin lara awọn oṣiṣẹ ileewe Chrisland School, ati ileewe naa funra ẹ, ti foju bale-ẹjọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọgbọnjọ, oṣu Kẹta, ọdun yii, lori iku ojiji to pa akẹkọọ ileewe ọhun to jẹ ọmọọdun mejila, Whitney Adeniran, loṣu to kọja.
Awọn oṣiṣẹ mẹrin ti wọn bẹrẹ si i kawọ pọnyin rojọ nile-ẹjọ giga apapọ kan to fikalẹ siluu Ikẹja, nipinlẹ Eko ni, Ọgbẹni Ademoye Adewale, Kuku Fatai, Abilekọ Belinda Amao ati Victoria Nwatu Ugochi.
Ijọba ipinlẹ Eko, lati ẹka to n ba araalu ṣẹjọ, Department of Public Prosecution (DPP) lo wọ awọn afurasi naa re kootu lori ẹsun meji. Awọn ẹsun meji ọhun da lori ipaniyan ati iwa aibikita, aiṣiṣẹ-ẹni-bii-iṣẹ.
Nigba ti Onidaajọ Oyindamọla Ọgala, to wa lori aga idajọ kootu naa bi awọn afurasi yii leere boya wọn jẹbi tabi wọn ko jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan wọn, wọn lawọn ko jẹbi.
Igbẹjọ naa ṣi n tẹsiwaju lasiko ta a fi n ko iroyin yii jọ.
Ẹ oo ranti pe, baba akẹkọọ to doloogbe yii, Ọgbẹni Adeyẹmi Adeniran, lo pariwo si gbogbo ọmọ Naijiria pe ki wọn gba oun lori iku aitọjọ tawọn alaṣẹ ileewe naa fi da ẹmi ọmọbinrin oun, Whitney, legbodo, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Keji, ọdun yii.
Baba yii ni nnkan kan ko ṣe ọmọ naa to fi mura, ti ọkọ ileewe wọn si waa gbe e lọ sibi ti wọn ti n ṣe ayẹyẹ ere idaraya onile-jile ti wọn n pe ni Inter-House Sport, eyi to waye ni Agege Stadium. Ṣugbọn lojiji ni wọn pe oun pe ọmọ naa ti ku. O ni iwa aibikita ati ailaamojuto awọn alaṣẹ ileewe naa lo pa ọmọ yii. Bakan naa lo fẹsun kan awọn alaṣẹ ileewe ọhun pe wọn fẹẹ dawọ bo ọrọ ọhun lori tori riri toun ri oku ọmọ oun, oun mọ pe iṣẹlẹ pajawiri kan lo ṣẹlẹ, ki i ṣe aarẹ tabi aisan. O ni irisi oku naa jọ ti ẹni ti ina mọnamọna gbe lojiji, ṣugbọn awọn alaṣẹ ileewe ko fẹẹ sọ ootọ foun.
Lẹyin eyi nijọba ipinlẹ Eko paṣẹ titi ileewe naa pa, ti wọn si bẹrẹ iwadii ati ayẹwo iṣegun lati mọ ohun to ṣokunfa ijamba yii ati iru iku to pa ọmọ yii gan-an.
Wọn ṣe ayẹwo ti wọn fi n ri fin-in idi koko iku to pa ẹnikan, esi ayẹwo naa si fidi ẹ mulẹ pe ina ẹlẹntiriiki lo gbe akẹkọọ yii, ki i ṣe aarẹ.
Eyi mu ki iwadii tẹsiwaju, ti wọn si fi pampẹ ofin mu awọn olujẹjọ mẹrin yii, wọn ni wọn lẹjọ i jẹ lori iku ọhun.
Ohun mi-in t’Alaroye gbọ ni pe ẹnikan to n fi ẹnjinni yan guguru ta nibi ayẹyẹ ere idaraya naa lo fa waya ina wọnu ẹnjinni rẹ, amọ apa kan lara waya naa ti bo, wọn ko si fi nnkan kan bo o tabi we nnkan mọ ibẹ, eyi ni wọn lọmọbinrin naa dasẹ le lojiji ti ina fi gbe e, tọrọ si fi yiwọ, bo tilẹ jẹ pe a o le fidi eyi mulẹ.