Iku akẹkọọ Fasiti OAU: Adajọ ti ju Adedoyin sẹwọn l’Abuja

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ile-ẹjọ giga ijọba apapọ to wa niluu Abuja ti kọ gbogbo arọwa agbẹjọro Dokita Ramon Adedoyin, ẹni to ni ileetura ti akẹkọọ Fasiti Ifẹ, Timothy Adegoke, ku si, lati maa jẹjọ ẹ lati ile.

Ṣaaju ni awọn agbẹjọro Adedoyin, eleyii ti Agbẹjọro Kunle Adegoke ko sodi ti gbe iwe ẹbẹ siwaju kootu lati fun olujẹjọ lanfaani si awọn ẹtọ to ni labẹ ofin.

Ẹtọ naa ni pe ki ile-ẹjọ fun un ni beeli, ko le ni anfaani lati maa jẹjọ lati ile titi ti awọn ọlọpaa yoo fi pari iwadii wọn.

Bakan naa ni Oloye Ṣẹgun Aworinde, ẹni to pe ara rẹ ni aburo Dokita Adedoyin sọ nile-ẹjọ pe aimọye igba loun ti sọ fun awọn ọlọpaa pe ẹgbọn oun ni aisan ẹjẹ-riru ati itọ ṣuga, sibẹ, awọn ọlọpaa ko fun un lanfaani lati lo oogun rẹ lati ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kọkanla, ti wọn ti mu un.

Aworinde fi kun ọrọ rẹ pe ẹni to ni ileeṣẹ kaakiri ni Adedoyin, bẹẹ lo ni awọn ileewe kaakiri ninu eyi ti Oduduwa University, Ile-Ifẹ, wa. O ni ọmọ ọdun marundinlaaadọrin ni, bi ko si ṣe lanfaani si itọju to peye lewu fun ilera rẹ.

O ni ti ile-ẹjọ ba fun un lanfaani beeli, ko le e sa lọ fun igbẹjọ, nitori pupọ ninu awọn okoowo rẹ lo wa lorileede Naijiria, ọrọ ilera rẹ lo si yẹ ki kootu boju wo bayii.

Ṣugbọn Onidaajọ Inyang Ekwo ko gba gbogbo arọwa yii wọle, dipo bẹẹ, o ni ki wọn ko gbogbo iwe ipẹjọ lọ sọdọ ẹni ti wọn doju iwe naa kọ, iyẹn ọga agba ọlọpaa patapata lorileede yii.

Lẹyin naa lo sun igbẹjọ si ọjọ kẹsan-an, oṣu kejila, ọdun yii.

Leave a Reply