Iku Buruji Kashamu: Idaamu ti ba awọn oloṣelu o

Ki i ṣe e pe ọkan wọn le naa tẹlẹ, ṣugbọn iku to waa pa ọkunrin oloṣelu pataki ipinlẹ Ogun, Oloye Ẹṣọ Jinadu ti wọn n pe ni Buruji Kaṣamu lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja yii, ti ko ọkan awọn oloṣelu gbogbo ni Naijiria soke gidigidi. Ni bayii, gbogbo ọna ni awọn olowo nla ninu wọn n wa lati kọja si ilu oyinbo, paapaa awọn orilẹ-ede ti wọn ti kapa arun Korona, nitori ohun ti wọn n ro ni pe awọn ko le gboju le iwadii ati ayẹwo awọn oniṣegun ni Naijiria, wọn ko si mọ boya arun naa ti wa lara awọn. Ohun to fa a ni pe ko too di pe arun naa jade sita lara awọn to n pa yii, yoo ti wa lara wọn fungba diẹ, ni gbogbo akoko yii ni wọn yoo si maa fi ara yira pẹlu awọn ọlọla ati oloṣelu ẹlẹgbẹ wọn, ọpọ awọn ti wọn si ba Buruji Kaṣamu ṣe lẹnu ọjọ mẹta yii ni wọn ti bẹrẹ si i paya poro, ibi ti kinni naa si bọ si lara wọn ko daa.

Ileewosan nla kan naa to jẹ ti awọn olowo, ti wọn royin pe owo ti wọn n gba nibẹ ki i duro lori ẹgbẹrun lasan, miliọnu miliọnu ni fun ẹni ti kinni naa ba ti mu, to si jẹ gbogbo wọn lo maa n pariwo pe ibẹ ni ki wọn gbe awọn lọ naa ni ko jọ pe o ṣiṣẹ fun wọn mọ yii, nitori o fẹrẹ jẹ pe ọpọ awọn olowo nla ti wọn n ru wọle sibẹ yii, oku wọn ni wọn n gbe jade. Abba Kyari ni wọn kọkọ gbe pamọ sibẹ, ti oun wa nibẹ titi, koda, awọn ara Eko ko mọ, ti wọn si tọju Korona naa titi to fi ja si iku fun un. Ibẹ naa ni wọn ru gomina ipinlẹ Ọyọ ana, Abiọla Ajimọbi lọ, ohun ti awọn eeyan si kọkọ gbọ ni pe o ti gbẹmi-in mi, ki iroyin mi-in too tun jade pe ko ma ti i ku o, o wa laaye to n ṣere, ti wọn lo ti gbadun lọṣibitu naa. Ṣugbọn nigbẹyin, irọ lọrọ naa pada ja si, nitori ni ọsibitu to wa naa, ko jade nibẹ laaye. Nibẹ lo ku si.

Eyi to ka awọn ara Eko lara ju ni ti awọn oloṣelu meji to gbajumọ bii iṣana ẹlẹẹta laarin wọn, Adebayọ Ọṣinọwọ ti wọn n pe ni Pẹpẹrito ati Ọtunba Tunde Burahimọ, ti wọn jọ ku laarin ọsẹ meji sira wọn. Ọrẹ lawọn mejeeji, aṣofin Eko si ni wọn, ọkan n bẹ ni Abuja, ekeji si wa nile-igbimọ aṣofin Eko, bi wọn ṣe ku lojiji bẹẹ ya araalu lẹnu. Korona naa lo pa wọn, ọsibitu ti wọn n gbe wọn lọ ni Ikoyi, l’Ekoo, yii naa ni wọn si gbe wọn lọ, nibẹ naa lawọn mejeeji yii si dakẹ si. Yatọ si awọn oloṣelu ti wọn ku yii, awọn olowo nla nla mi-in naa ti ku sọhun-un ti ko si araalu to mọ, nitori orukọ tiwọn ko fi bẹẹ si laarin igboro. Awọn iṣẹlẹ yii ti n jẹ ki ọkan awọn oloṣelu nla nla nilẹ yii ko soke tẹlẹ, nitori wọn ti bẹrẹ si i ri i pe ko daju pe ileewosan Ikoyi yii yoo gba awọn bi kinni naa ba mu awọn, ọna ati lọ siluu oyinbo ni wọn si n wa, koda nigba ti ko sẹni to ti i sọ pe Koro ti mu wọn.

ALAROYE gbọ pe lara ohun to jẹ ki wọn tete gbe iyawo Aarẹ ilẹ wa, Ọgagun agba Muhammadu Buhari, lọ siluu oyinbo ree, nitori wọn ko mọ pato arun naa, awọn dokita si ti sọ fun wọn pe ko si ọna ti arun Korona yii ki i ba wa, o le gba ibi ọrun didun tabi nnkan mi-in, ki ọrọ naa si too di baami-in, ni wọn ṣe yaa gbe obinrin naa jade lọ si Dubai. Bo ba jẹ ti tẹlẹ ni, o ṣee ṣe ko jẹ ọsibitu Eko yii ni wọn yoo gbe e wa, nibi ti yoo ti maa gba itọju rẹ lọ, ṣugbọn ọsibitu naa ti di ijaya bayii, awọn olowo ko si mọ eyi ti wọn yoo ṣe. Iku ti Buruji Kaṣamu yii lo tubọ waa fa gulegule ti ọkan wọn n ṣe bayii, nitori wọn mọ pe bo ba jẹ apa owo ka kinni yii ni, ko si ọna ti wọn ti beere owo, ko si si iye ti wọn yoo beere ti yoo jẹ nnkan kan loju Kaṣamu, nigba to jẹ agbọn-ọn-gbẹ lowo to ni. Ṣugbọn o han pe apa owo ko ka kinni naa lọsibitu yii, ọrọ naa si toju su gbogbo alagbara.

Ayọdele Fayoṣe ati Oluṣẹgun Ọbasanjọ

Ṣebi ni bii ọsẹ meji sẹyin ni iroyin naa kọkọ jade pe Buruji Kasamu ti ni arun Korona, ṣugbọn nigba to jẹ kinni naa ti di kari aye, to si jẹ awọn gomina mi-in ti wọn n pariwo pe awọn ni in ki i pẹẹ jade lai ku, to si jẹ ile wọn ni wọn yoo wa, bii ti El-Rufai ni Kaduna, Arakunrin Akeredolu ni Ondo, Kayọde Fayẹmi ni Ekiti, atawọn mi-in bẹẹ, ọpọ eeyan ti fọkan si i pe bi ọkunrin naa ti wọ ọṣibitu ni yoo jade. Afi bo ṣe ya ti ko sẹni to tun gbọ kinni kan, ti wọn ni wọn ti gbe e lọ si ọṣibitu awọn olowo to wa ni Ikoyi, l’Ekoo yii. Sibẹ naa, ko sẹni to ro pe yoo tori eyi ku, wọn ni yoo jade nibẹ laipẹ, yoo si maa pada waa ṣe awọn ohun to n ṣe laarin ilu lọ. Awọn oloṣelu to jẹ oun ni agbojule wọn ninu ẹgbẹ PDP, paapaa ti ipinlẹ Ogun n duro de e, pe oun ni yoo jẹ ki ẹgbẹ naa gbajọba ipinlẹ naa ni ọdun 2023, nitori oun lo ku to n nawo ẹgbẹ naa lati igba to pẹ wa. Bakan naa ni awọn mẹkunnu to maa n ṣe loore nile rẹ naa n reti pe ko ni i pẹẹ de.

Ohun to jẹ ki iku naa jẹ agbọ-sọgba-nu nigba ti wọn gbọ ree, ko si sẹni kan to tete gba iroyin naa gbọ, eebu lawọn mi-in si n bu awọn oniroyin ti wọn kọkọ gbe jade, wọn ni iroyin ẹlẹjẹ lasan ni. Ṣugbọn nigba ti yoo fi to bi wakati meji ti iroyin akọkọ jade, o han pe ko si ariyanjiyan ninu kinni naa mọ, awọn eeyan gba ni tootọ pe iku ti mu Kaṣamu lọ. Bi arun Korona yii si ti wa nita to, latigba tawọn eeyan ti gbọ iku rẹ ni wọn ti n rọ lọ si ile rẹ ni ilu Ijẹbu-Igbo, awọn mi-in ko si kuro nile naa titi ti wọn fi gbe oku rẹ de, wọn fẹẹ foju ara wọn ri i pe loootọ lo ti ku. Ohun to ya awọn eeyan lẹnu ju ni pe ko sẹni to gbagbọ pe ero yoo pọ to bẹẹ nibi oku ẹni kan lasiko ti ajakalẹ-arun Koro yii n ja kiri bayii, ati bi wọn ti sọ pe ẹnikẹni ko gbọdọ jade, ti wọn si n kilọ pe ki awọn eeyan ma sun mọ ara wọn rara, ki wọn jinna sira wọn ni gbangba.

Awọn eeyan yii lawọn ko le jinna si ara wọn, awọn miiran si fẹẹ fọwọ kan oku rẹ, wọn ni oloore awọn ni. Nigba naa ni awọn eeyan pupọ too mọ pe Kaṣamu ti wọn n gbọ orukọ rẹ, pe oloṣelu ni, po wa lara awọn ti wọn n ko owo jẹ, tabi pe ẹni kan to ni ẹjọ niluu oyinbo ti awọn oyinbo n wa ni, yatọ pata si Kaṣamu ti awọn ara Ijẹbu ati agbegbe rẹ mọ. Wọn ni ni gbogbo igba ni i fi owo gidi ṣaanu ni agbegbe naa, bẹẹ ni ki i ṣe owo ounjẹ lo n fun wọn, owo ti wọn yoo fi da ara wọn lokoowo, owo ti wọn yoo fi le ṣe daadaa, tabi owo lati ran awọn ọmọ nileewe lo maa n fun wọn. Ọpọ akẹkọọ lo si wa nileewe to jẹ oun lo n san owo wọn. Nidii eyi ni gbogbo awọn ero ṣe rọ jade, ti wọn si tẹle oku rẹ de gbagede ti wọn sin in si. Bo tilẹ jẹ pe awọn ọlọpaa wa nibẹ, agbara ati isapa awọn naa ko ka ero ọhun mọ, wọn fi wọn silẹ, wọn n woran ni. Bi awọn mi-in ti n ke paapaa ni wọn n gbara dalẹ, wọn n pariwo pe oloore awọn ti lọ.

Ohun to jẹ ki awọn mi-in binu si aarẹ tẹlẹ, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, niyi. Aarẹ ana naa sọ pe Buruji Kaṣamu lo ọgbọn ati ete lati sa fun awọn adajọ aye, ṣugbọn ko le sa fun awọn ọlopaa ati adajọ ọrun. Awọn eeyan binu si baba naa pe ko daa ko sọ bẹẹ si oku ọrun, awọn ti wọn si ti jẹ ninu owo Buruji ni gbọọrọgbọọrọ lo fi san ju Ọbasanjọ to n sọrọ yii lọ. Koda, gomina Ekiti tẹlẹ, Ayọdele Fayoṣe, da sọrọ naa, o lo ti mọ Ọbasanjọ lara ko maa ṣe bii angẹli, bii ẹni ti ko ni abawọn lara, bẹẹ irọ ni baba naa n pa, ọwọ oun naa ko mọ. Bakan naa ni Aṣiwaju Bọla Tinubu si sọ o, lẹyin to ti daro iku to pa Buruji Kaṣamu tan, o ni ko daa ki ẹnikẹni maa sọrọ abuku tabi eebu si oku ọrun.

Yatọ si awọn yii ṣaa, ogunlọgọ awọn oloṣelu atawọn olowo ni wọn n daro iku ọkunrin naa. Ṣugbọn nisalẹ ikun wọn, ẹru n ba wọn, idaamu si ba wọn, nitori awọn naa mọ pe iku to n pa ojugba ẹni, owe lo n pa fun ni. Bẹẹ ni ko seyii to n dun wọn ju nibẹ ju ilu oyinbo ti wọn ko ti i ri ọna lọ. Awọn oyinbo ni ki wọn ma ti i wa, wọn ni ẹni to ba ti wa, wọn yoo karantain ẹ, bi wọn ba si ti ri i pe o ni Koro, wọn yoo da a pada sibi to ti n bọ ni. Ni tootọ, ko si igba kan ti idaamu ba awọn oloṣelu ati olowo ni Naijiria to bayii ri, ti asiko yii le koko fun wọn ju.

3 thoughts on “Iku Buruji Kashamu: Idaamu ti ba awọn oloṣelu o

  1. Bi Iwo base rere ara kiyoayao…enijegbi yooku gbigbi…imorab misieyin tokunipe emowuleberu..eru man nwu aisan jade ninu ara ni….solution nipee elo maa fi a won owo teeko pama fun awan talaka….epe ibite bawade in oriede yi lonjayin…kcorona kan je sababi lasan ni

  2. Igba ti aobatitun ile se tele bosema n ri niyen .olodumare afijin awon tontiku. Olodumare ajeki odun kojinna sodun. Irunmole abawapano aisan buburu

Leave a Reply