Iku Odumakin: Ina wa ku lojiji, igi nla wo niluu Moro- Olumoro

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Olumoro ti ilu Moro ti i ṣe ilu abinibi Oloogbe Yinka Odumakin, Ọba Abidoye Oyeniyi, ti ṣapejuwe iku ọkunrin naa gẹgẹ bii igi nla to wo laipe ọjọ, to si jẹ adanu nla fun gbogbo awọn ọmọ ilu naa.

Olumoro, ẹni ti iyawo rẹ, Olori Irene Oyeniyi, gbẹnu sọ fun, ṣalaye fun ALAROYE lasiko ti akọroyin wa ṣabẹwo saafin pe ina nla lo ku lojiji niluu naa, gbogbo ẹni to ba si mọ riri ọlọpọlọ pipe yoo maa figba gbogbo ranti rẹ.

O ni ipa ti Odumakin ko lorileede yii pẹlu bo ṣe jẹ akinkanju ko le parẹ ninu itan laelae, bẹẹ ni ilu Moro ko le gbagbe ọkunrin naa.

Ninu iroyin mi-in, Gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Adegboyega Oyetọla, ti ranṣẹ ibanikẹdun si ẹgbẹ Afẹnifẹre lori iku agbẹnusọ wọn, Ọgbẹni Yinka Odumakin.

Ninu atẹjade ti Akọwe iroyin fun gomina, Ismail Omipidan, fi sita, Oyetọla kẹdun pẹlu iyawo oloogbe naa, Dokita Joe Odumakin, awọn ọmọ, ati gbogbo mọlẹbi ọkunrin naa.

O ṣapejuwe iku Odumakin gẹgẹ bii adanu nla fun iran Yoruba ati orileede yii lapapọ nitori ipa to ko ninu imuduro ati idagbasoke ijọba tiwa-n-tiwa lorileede yii ko kere rara.

Gomina fi kun ọrọ rẹ pe Odumakin jẹ ẹni to maa n wa idajọ ododo, iṣejọba tootọ ati orileede Naijiria to ṣee mu yangan.

O waa gbadura pe ki Ọlọrun tu gbogbo mọlẹbi rẹ ninu, ki iku rẹ ma si jẹ akufa.

 

Leave a Reply