Iku oro o! Eeyan meji ku ninu kẹke Marwa l’Okoko, tirela lo pa wọn

Aderounmu Kazeem

Aṣalẹ ọjọ Ẹti, Fraidee to kọja yii lawọn eeyan meji kan pade iku ojiji ninu Kekẹ Marwa ti wọn wọ nigba ti tirela kọlu wọn lagbegbe Okokomaiko ni ipinlẹ Eko.

Ohun ti ALAROYE gbọ ni pe nibi ti awakọ tirela to ṣeku pa awọn eeyan yii ti n ya fun koto ni bositọọbu Mẹkaniiki lojuna Eko si Badagry lo ti kọlu Kẹkẹ Marwa to n bọ jẹjẹ ẹ pẹlu awọn eeyan kan ninu, ti meji si ku ninu awọn ero ọhun loju-ẹsẹ.

Ẹni kẹta to wa ninu kẹkẹ Marwa, iyẹn ẹni to n wa a. nikan ni ko ba iṣẹlẹ ọhun lọ, ṣugbọn niṣe ni ẹsẹ ẹ mejeeji kan, ti wọn si sare gbe e lọ si ọsibitu.

A gbọ pe, wọn ti gbe oku awọn mejeeji ọhun si mọṣuari, bẹẹ lawọn eeyan agbegbe naa ti sọ pe, ọpọlọpọ koto ati oju ọna ti ko dara laduugbo naa lo n fa ijamba ọkọ lọpọ igba.

 

Leave a Reply