Iku pa olori awọn Amọtẹkun kan l’Ọyọọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ọkan ninu awọn adari ẹṣọ Amọtẹkun, ẹka ipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Tajudeen Ìdòwú Salaudeen, ti jade laaye. Ọkunrin yii ni olori awọn Amọtẹkun ijọba ibilẹ Kajọla, ni ipinlẹ yìí. Ọkunrin yii ṣalaabapade iku ojiji lasiko ijamba ọkada to ṣẹlẹ sí i laaarọ Ọjọbọ, Tọsidee ọse ta a lo tan yii.

ALAROYE gbọ pe ilu Okeho lọmọ bibi Ilero yii n gun alupupu rẹ lọ ni idaji Ọjọbọ, ko to too gba ipe lori foonu rẹ pe iṣẹ pajawiri kan n duro de e niluu abinibi ẹ.

Kò pẹ pupọ to pada sọna Ilero nijanba ọhún ṣẹlẹ sí i, to sí dagbere faye lẹyin iṣẹju diẹ to ṣubú lori alupupu naa.

Oludari agba ẹṣọ Amọtẹkun nipinlẹ Ọyọ, Ajagun-fẹyinti Ọlayinka Ọlayanju, fidi ẹ mulẹ pe laaarọ Tọsidee nijanba to gbẹmi ọga ikọ Amọtẹkun nijọba ibilẹ Kajọla yii waye, aarọ Furaidee ni wọn sinkú ẹ̀ nilana isinku Musulumi

Leave a Reply