Ile akọku ni Yisa ko awọn ọmọ ọdun meje, marun-un lọ, to si fipa ba wọn lo pọ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọwọ ẹṣọ Amọtẹkun ipinlẹ Ọṣun ti tẹ ọmọkunrin ẹni ọdun mejilelọgbọn kan, Yisa, lori ẹsun pe o fipa ba awọn ọmọ keekeeke meji lo pọ.

Agbegbe Aképè, niluu Oṣogbo, la gbọ pe Yisa, to n ṣiṣẹ alapata naa n gbe pẹlu awọn obi awọn ọmọdebinrin yii.

ALAROYE gbọ pe nnkan ipanu ni ọkunrin alapata yii maa n ra fun awọn ọmọ ti ọkan lara wọn jẹ ọmọ ọdun meje, ti ekeji si jẹ ọmọ ọdun marun-un ọhun tẹlẹ.

Lọjọ Tọsidee to kọja yii, iyẹn ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii ni Yisa tan awọn ọmọ mejeeji ọhun wọnu ile akọku kan laduugbo naa, to si fipa ba wọn laṣẹpọ.

Awọn araadugbo ti wọn ri i bi awọn ọmọdebinrin yii ṣe n jade ninu ile naa lẹyọkọọkan ko too di pe Yisa jade ni wọn lọ fi ọrọ naa to awọn Amọtẹkun leti, ti wọn si fi panpẹ ofin gbe e.

Gẹgẹ bi Olori ẹṣọ Amọtẹkun l’Ọṣun, Ajagunfẹyinti Bashir Adewinmbi, ṣe sọ, o ni iwadii fihan pe afipabanilopọ ni Yisa, ọdaran paraku si ni pẹlu.

Adewinmbi dupẹ lọwọ awọn eeyan agbegbe naa fun bi wọn ko ṣe fọwọ bo iwa ọdaran mọlẹ, ti wọn si fọwọsowọpọ pẹlu ẹṣọ Amọtẹkun lori iṣẹlẹ naa.

O ni awọn ti fa Yisa le awọn ọlọpaa lọwọ fun itẹsiwaju iwadii, ireti si wa pe yoo foju ba ile-ẹjọ laipẹ.

Leave a Reply