Ile alaja mẹta ti wọn n kọ lọwọ da wo l’Ekoo

Jọkẹ Amọri

Ile alaja mẹta kan ti wọn n kọ lọwọ to wa ni Akanbi Crescent, ni agbegbe Yaba, niluu Eko, la gbọ pe o ti da wo bayii lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ yii.

O tun da wo si ile kan to wa lẹgbẹẹ ile naa lori. ALAROYE gbọ pe lọdun to kọja ni apa kan ile naa da wo, ṣugbọn awọn to n kọle naa ko dawọ duro, wọn n kọ ọ lọ ni, bo tilẹ jẹ pe awọn araadugbo naa pe akiyesi awọn agbofinro si i nigba naa.

A gbọ pe awọn araadugbo naa ti ranṣẹ pe ileeṣẹ to n mojuto ijamba pajawiri nipinlẹ Eko, (Lagos State Emergency Management) lati waa doola awọn to ṣeeṣe ko wa labẹ ile naa.

Ko ti i sẹni to mọ iye eeyan to wa labẹ ile naa lasiko ta a n ko iroyin yii jọ. Ọdọmọkunrin kekere kan ati agbalagba kan la gbọ pe wọn ti ri yọ jade kuro ninu awoku ile naa.

Leave a Reply