Ile-ẹjọ sọ awọn mẹrin to paayan sẹwọn l’Ogbomọṣọ, iya meji lo bi awọn mẹrẹẹrin

Ọlawale Ajao, Ibadan

Fun bi wọn ṣe pa ọkunrin kan lai ṣẹ, lai ro, awọn ọmọ iya kan naa, Azeez Kareem ati Usman Kareem pẹlu Oyeleke Amọle ati Tunde Amọle, ti awọn naa tun jẹ tẹgbọn taburo ti dero ahamọ ọgba ẹwọn bayii.

Awọn mẹrẹẹrin yii la gbọ pe wọn lọọ ṣa eeyan ladaa pa nitori ọrọ ilẹ, bẹẹ ija naa ko kan wọn, wọn kan da bii agbowo ita lori ilẹ ọhun lasan ni.

Lọjọ kẹta, oṣu karun-un, ọdun 2020 yii, niṣẹlẹ ọhun waye nigba tawọn ẹruuku yii lọọ ka baba kan ti wọn n pe ni Debọ Thomas Oluṣọla pẹlu awọn ti wọn n ba a ṣiṣẹ ninu oko ẹ to wa laba Oke-Igba, niluu Ogbomọṣọ, mọ inu oko naa, ti wọn si ṣe Ọgbẹni Aminu Moruf, awakọ katakata to n kọ ebe ninu oko naa leṣe.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, o pẹ diẹ ti Ọgbẹni Oluṣọla ati ẹnikan ti n ja si ilẹ yii. Lọjọ kẹrin, oṣu kẹfa, ọdun yii, lọrọ naa di yanpọnyanrin nigba ti ẹni ti wọn jọ n ja silẹ ko awọn tọọgi lọọ kọlu wọn lori ilẹ naa.

Awakọ katakata ti wọn fi n ṣiṣẹ ninu oko ọhun, Ọgbẹni Moruf, lo fori fa a pẹlu bo ṣe jẹ pe oun lawọn ẹruuku yinbọn mọ. ṣugbọn kinni ọhun ko la ẹmi ẹ lọ nitori itan nibọn ti ba a.

Ṣugbọn nibi ti wọn ti n gbe awakọ yii lọ sileewosan lọjọ keji lawọn janduku yii ti tun da wọn lọna, ti wọn si ṣa awakọ naa ladaa lagbari ati lorikeerikee ara titi to fi dagbere faye.

Lẹyin ti baba onilẹ, Ọgbẹni Oluṣọla, atawọn eeyan ẹ ti sa asala fẹmi-in ara wọn ni wọn lọọ fiṣẹlẹ ọhun to awọn agbofinro leti ni teṣan ọlọpaa to wa laduugbo Owode, niluu Ogbomọṣọ.

L’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja lawọn ọlọpaa gbe awọn mẹrẹẹrin lọ si kootu, ẹsun marun-un ọtọọtọ to ni i ṣe pẹlu ipaniyan ati lilo ohun ija oloro lọna ti ko bofin mu ni wọn fi kan wọn ni kootu Majisireeti to wa niluu Ogbomọṣọ.

Agbẹjọro awọn ọlọpaa, Amofin Olajide James Famuyini, to gbẹjọ lọ si kootu naa lo tun sọ pe awọn ni lati gbe ẹjọ naa lọ si ileeṣẹ eto ofin ijọba Ọyọ fun imọran lori bi wọn ṣe maa tun ẹjọ naa pe sile-ẹjọ giga nitori pe ile-ẹjọ Majisireeti ko lagbara lati gbọ ẹjọ naa.

Amọ ṣa, Onidaajọ Muideen Salami, ti sun ẹjọ naa si ọjọ kẹrinla, oṣu kẹjọ, ọdun 2020 yii. O waa paṣẹ pe ki wọn fi awọn olujẹjọ naa si ahamọ ọgba ẹwọn titi dọjọ naa.

Leave a Reply