Ile-ẹjọ ti da ẹjọ DPO to fiya jẹ telọ rẹ n’Ibadan nu

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ile-ẹjọ Majisireeti to wa laduugbo Iyaganku, n’Ibadan, ti da ẹjọ ti DPO teṣan Iyaganku, CSP Alex Sanni Gwazah, pe telọ rẹ nu, wọn lẹjọ ọhun ko fi ibi kankan nilaari.

CSP Gwazah lo pe telọ rẹ to n jẹ Lukman Adeniyi lẹjọ lọsẹ to lọ lọhun-un, o ni kile-ẹjọ ba oun fiya jẹ ẹ nitori ti ko ran aṣọ ti oun gbe fun un daadaa.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbe e jade lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrin, oṣu kọkanla, ọdun 2020 ta a wa yii, ọkan ninu awọn onibaara telọ yii lo mu un mọ ọga ọlọpaa teṣan Iyaganku, ti iyẹn si gbe oriṣii aṣọ mejila fun un lati ran lẹẹkan naa.

Ẹgbẹrun lọna ọgọta Naira (N60,000) l’Adeniyi beere gẹgẹ bii owo iṣẹ ati owo ti oun yoo fi ra gbogbo ohun eelo ti yoo pari gbogbo aṣọ naa, ti CSP  Gwazah si fara mọ ọn.

Ṣugbọn nigba ti baba telọ gbe awọn aṣọ naa lọọ fun ọga DPO ni teṣan rẹ ni Iyaganku lẹyin to pari iṣẹ tan, kaka ki ọga ọlọpaa sanwo iṣẹ baba naa lẹyin to ti gba aṣọ lọwọ ẹ, igbaju olooyi lo ko bo o, o ni ko ran awọn aṣọ naa tẹ oun lọrun, bẹẹ ni ko fun ẹniẹlẹni lowo iṣẹ to ṣe.

Ṣugbọn lẹyin ti telọ yii ti lọ tan nibinu ọga ọlọpaa tun fọgbọn tan baba naa wa si teṣan rẹ, to si ti i mọle.

Lẹyin ọjọ meji ti baba onibaba lo latimọle lọga ọlọpaa tun gbe e lọ si kootu to si paṣẹ fun ile-ẹjọ lati tun fiya mi-in jẹ telọ rẹ naa nitori oriṣii aṣọ mejila ọtọọtọ ti oun ra pẹlu ẹgbẹrun mọkanlelọgọsan-an Naira (181) lọkunrin naa ran ni irankuran-an, to si ṣe bẹẹ fi oun lowo ṣofo.

Ṣugbọn olujẹjọ sọ pe oun ko jẹbi ẹsun ọdaran, olujẹjọ kan n lo agbara rẹ nilokulo le oun lori ni nitori ẹgbẹrun lọna ọgọta Naira (N60,000) loun fi ra awọn nnkan eelo ti oun fi ran awọn aṣọ naa, ṣugbọn niṣe lọga ọlọpaa yii kan gba awọn aṣọ naa lọwọ oun lai san kọbọ foun.

Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii ni igbẹjọ ọhun tun waye, olupẹjọ ko yọju si kootu gẹgẹ bii iṣe rẹ lọjọ ti igbẹjọ naa kọkọ waye. Awijare to fun ile-ẹjọ ni pe iṣẹ ni ko jẹ ki oun raaye, oun wa lara igbimọ ti ọga agba ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Joe Nwachukwu Enwonwu, gbe kalẹ lati ṣewadii nipa rogbodiyan to waye latari ifẹhonu lodi si SARS laipẹ yii.

Sajenti Gbemisọla Adeniyi to gbe olujẹjọ lọ si kootu lorukọ ọga ẹ ni DPO Iyaganku ran niṣẹ naa. Ṣugbọn bo ṣe jiṣẹ ọhun tan lagbẹjọro olujẹjọ, Amofin Jubril Muhammed, ti sọ niwaju adajọ pe irọ gbuu lolupẹjọ n pa, oun ti ṣewadii lori awijare rẹ, iwadii si fi han pe ko si lara awọn igbimọ to n ṣewadii rogbodiyan iwọde naa.

Nigba to n rọ ile-ẹjọ lati da ẹjọ naa nu, Amofin Muhammed sọ pe ohun ti ofin sọ ni pe bi eeyan ba pẹjọ, ti ko si yọju si kootu ni gbogbo asiko ti igbẹjọ ba waye, iru ẹjọ bẹẹ ko lẹsẹ nilẹ niyẹn, ile-ejọ sin i lati da a nu ni.

Iyẹn l’Onidaajo-binrin Akande ṣe da ẹjọ naa nu, o lẹjọ ọhun ko lẹsẹ nilẹ rara.

Leave a Reply