Ile-ẹjọ ṣekilọ: Buhari ati CBN ko gbọ fi kun ọjọ ti wọn yoo fi paarọ owo atijọ mọ

Faith Adebọla

K’eku ile gbọ ko sọ fun toko o, ki adan gbọ ko si lọọ ro foobẹ, ireti awọn ti wọn rọ Aarẹ Muhammadu Buhari ati banki apapọ ilẹ wa lati sun gbedeke nina ati pipaarọ owo atijọ si tuntun ti ja si pabo, pẹlu bile-ẹjọ giga kan lolu-ilẹ wa ṣe paṣẹ pe ijọba ko gbọdọ fi ọjọ kan kun gbedeke naa, wọn ni gbogbo sagba-sula lori pipaarọ owo naa ko gbọdọ kọja ọjọ kẹwaa, oṣu Keji, ọdun 2023, ti i ṣe ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, gẹgẹ bo ṣe wa lakọọlẹ tẹlẹ.

Ọsan ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹfa, oṣu Keji yii, ni Adajọ Eleojo Enenche, ti ile-ẹjọ giga ijọba apapọ kan to fikalẹ siluu Abuja, lolu-ilu ilẹ wa gbe aṣẹ naa kalẹ. Ninu ẹjọ kan ti marun-un ninu awọn ẹgbẹ oṣelu mejidinlogun to wa nilẹ wa pe, eyi ti nọmba iwe ipẹjọ rẹ jẹ FCT/HC/CV/2234/2023.

Kootu naa paṣẹ pe bayii pe:
“A pa a laṣẹ pe eyikeyii ninu awọn olujẹjọ wọnyi, iyẹn banki apapọ ilẹ wa (CBN), minisita feto idajọ, Aarẹ Muhammadu Buhari ati awọn yooku, ko gbọdọ yiri gbedeke ọjọ ti opin yoo de ba nina ati lilo owo atijọ igba Naira, ẹẹdẹgbẹta Naira ati ẹgbẹrun kan Naira tayọ ọjọ kẹwaa, oṣu Keji, ọdun 2023, bẹẹ ni awọn olujẹjọ wọnyi, tabi aṣoju wọn eyikeyii, ejẹnti wọn, oṣiṣẹ wọn, titi kan awọn banki to n ṣiṣẹ labẹ wọn ati awọn alabadowopọ wọn kankan ko gbọdọ sun gbedeke naa siwaju titi digba ti idajọ yoo fi waye lori ẹsun ati ẹbẹ ti olupẹjọ yii tẹ pẹpẹ rẹ siwaju kootu yii.”

Aṣẹ yii ti ta ko ẹbẹ awọn gomina ipinlẹ mẹta kan, Nasir El-Rufai ti Kaduna, Yahaya Bello ti ipinlẹ Kogi, ati Bello Matawale ti Zamfara, tawọn ti kọkọ pẹjọ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹfa, oṣu Keji yii kan naa, lati rọ ile-ẹjọ giga to ga ju lọ nilẹ wa, Supreme Court, pe ki wọn paṣẹ fun Buhari ati banki apapọ, ki wọn sun gbedeke naa siwaju, wọn ni ipọnju ati inira ti ọrọ owo naa n fa fawọn eeyan ipinlẹ wọn buru gidi ni.
Ile-ẹjọ ti idajọ n pari si naa ko ti i mu ọjọ ti wọn yoo gbọ ẹsun yii, bẹẹ ni wọn ko ti i gbe aṣẹ tabi ipinnu kan kalẹ.

Bẹẹ, lọjọ Mọnde yii lawọn ẹgbẹ oṣelu mẹtala ninu mejidinlogun to wa nilẹ wa faake kọri p’awọn o ni i gba, awọn o si ni i fara mọ ọn ti banki apapọ ba fi le sun gbedeke naa siwaju kọja ọjọ kẹwaa, oṣu Keji, niṣe lawọn maa yọwọ yọsẹ ninu eto idibo to n bọ yii.

Leave a Reply