Ile-ẹjọ bẹrẹ igbẹjọ awọn to fipa ba akẹkọọ Fasiti Ilọrin lo pọ to fi ku

Ibrahim Alagunmu Ilọrin

Ile-ẹjọ giga ipinlẹ Kwara, ti bẹrẹ igbẹjọ lori awọn afurasi mẹjọ ti wọn fi pa ba Ọlajide Blessing, akẹkọọ Fasiti Ilọrin lo pọ, ti wọn tun ṣeku pa a, ni agbegbe Tankẹ Oke-Odo, ilu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, Onidaajọ Adebayọ Yusuf ni yoo maa gbọ ẹjọ wọn.

Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii, ni wọn gbe awọn afurasi mẹjọ ti wọn fipa ba Ọlajide Blessing lo pọ, ti wọn tun seku pa a, wa sile-ẹjọ, ti wọn si fi ẹsun mọkanla kan wọn. Lara ẹsun ti wọn fi kan wọn ni, igbimọpọ ṣiṣẹ ibi, idigunjale, ifipa-ba-ni-lo-pọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Agbẹjọro agba nipinlẹ Kwara, to tun jẹ Kọmisanna lẹka eto idajọ, Salman Jawondo, sọ pe oun ni yoo ṣaaju awọn igbimọ agbẹjọro yooku lati ri i pe idajọ ododo fẹsẹ mulẹ, tawọn yoo si gba agbẹjọro fun awọn afurasi naa ti wọn ko ba ni agbẹjọro titi di igba ti igbẹjọ miiran yoo maa waye. Wọn ti waa sun igbẹjọ si ọjọ kẹfa, oṣu keje, ọdun yii.

 

Leave a Reply