Ile-ẹjọ da awọn OPC Ibarapa mẹta ti wọn sọ sẹwọn nitori Iskilu Wakili silẹ

Faith Adebọla, Eko

Ṣe ẹ ranti awọn ọmọ ẹgbẹ OPC (Oodua Peoples’ Congress) mẹta, Awodele Adedigba, ẹni ọdun marundinlaaadọta, Dauda Kazeem, ẹni ọdun mejidinlogoji, ati Hassan Ramon, ẹni ọdun mẹtalelogoji, tawọn agbofinro sọ sahaamọ lọjọ keje, oṣu kẹta, ọdun yii, latari ẹsun ti wọn fi kan wọn pe wọn kopa ninu bi wọn ṣe lọọ mu olori awọn Fulani, Iskilu Wakili, labule Kajọla, niluu Ayetẹ, lọjọ keje, oṣu kẹta, ọdun yii?

Ile-ẹjọ Majisreeti Keji to wa n’Iyaganku, Ibadan, nipinlẹ Ọyọ, ti da awọn mẹtẹẹta silẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, wọn ni wọn ko mọwọ mẹsẹ, ati pe ko si ẹri kan pe wọn jẹbi iwa ọdaran lọjọ iṣẹlẹ ọhun, yatọ si bawọn ọlọpaa ṣe sọ.

Adajọ Hamzat Ọlajide lo paṣẹ itusilẹ ọhun ni awọn ọlọpaa ko le pese ẹri to pọ to lati fihan pe awọn ti wọn mu yii tẹ ofin loju, ko si si idi fun ile-ejọ lati fiya jẹ alaiṣẹ, tori naa, o nile-ẹjọ da ẹjọ naa nu bii omi iṣanwọ, ki wọn da awọn afurasi naa silẹ lalaafia loju-ẹsẹ.

Lati kootu naa lawọn afurasi naa ti buwọ luwe to yẹ, ti wọn si ti dẹni ominira.

Ọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ OPC ati awọn ọdọ agbegbe Ibarapa lo wa si kootu ọhun lati wo bi igbẹjọ naa yoo ṣe lọ si, wọn si fi idunnu wọn han nigba ti adajọ paṣẹ ominira fawọn olujẹjọ mẹtẹẹta.

Tẹ o ba gbagbe, Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹta, ni wọn kọkọ foju awọn olujẹjọ mẹtẹẹta bale-ẹjọ, wọn si ka ẹsun si wọn lẹsẹ. Lara ẹsun naa, bi agbefọba, Inpẹkitọ Ọpẹyẹmi Ọlagunju, ṣe ṣalaye niwaju adajọ pe wọn dana sun ile onile pẹlu dukia to to miliọnu marun-un to jẹ ti Iskilu Wakili, o ni wọn ṣika pa obinrin ẹni ọdun marundinlaaadọta kan nigba iṣẹlẹ ọhun, ati pe wọn gbimọ-pọ lati huwa ọdaran, wọn si ṣedajọ lọwọ ara wọn.

O lawọn ẹsun naa ta ko iwe ofin iwa ọdaran ipinlẹ Ọyọ, labẹ isọri okoolelọọọdunrun o din mẹrin (316), okoolelọọọdunrun ati mẹrin (324) ati ojilenirinwo o le mẹta (442).

Adajọ ile ẹjọ naa, Ọlajide Hamzat, paṣẹ lọjọ ọhun pe ki wọn maa ko awọn olujẹjọ mẹta yii lọọ sọgba ẹwọn Abolongo, nipinlẹ Ọyọ, titi tawọn yoo fi gba imọran lọdọ ajọ to n gba ile-ẹjọ nimọran, o si sun igbẹjọ si ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹrin.

Ṣugbọn igbẹjọ ko le waye lọjọ ti wọn sun un si ọhun latari iyanṣẹlodi awọn oṣiṣẹ kootu to n lọ lọwọ nigba naa, eyi lo mu ki igbẹjọ naa ṣẹṣẹ waye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejilelogun, oṣu kẹfa yii, lẹyin ti iyanṣẹlodi ti wa sopin losẹ to kọja lọhun-un.

Leave a Reply