Ile-ẹjọ da ẹjọ ti APC pe ta ko iwe-ẹri Gomina Ọbasẹki nu

Ṣinkin bii ẹni jẹ tẹtẹ oriire ni inu Gomina ipinlẹ Edo, Gaius Ọbaseki, ati awọn alatiyẹn rẹ n dun bayii, orin iṣẹgun si ni baba naa mu bọnu latari bi ile-ẹjọ giga apapọ kan to fikalẹ siluu Abuja ṣe da ẹjọ ti wọn pe ta ko iwe-ẹri rẹ nu.

Ọsan ọjọ Abamẹta, Satide yii, nile-ẹjọ naa gbe idajọ rẹ kalẹ. Adajọ Ahmed Mohammed ni ẹjọ olooraye lẹjọ ọhun, o ni wọn kan fẹẹ fakoko ile-ẹjọ ṣofo lasan ni.

Adajọ ni olupẹjọ yii ya ọlẹ debii pe wọn ko tilẹ le lọọ ṣayẹwo ni Fasiti Ibadan (UI) ti olujẹjọ naa sọ pe oun ti gba iwe-ẹri oun, boya loootọ lohun to sọ ri bẹẹ abi ko ri bẹẹ, bẹẹ ni wọn o lọ sọdọ ajọ Wayẹẹki lati fidi ẹsun ti wọn fi kan olujẹjọ mulẹ, o ni ṣe wọn o mọ pe ẹni to ba peeyan lẹjọ lo maa ṣiṣẹ wiwa ẹri lati fi gbe ẹsun rẹ lẹsẹ ni.

O ni ko si eyikeyii ninu awọn ẹlẹrii olupẹjọ to le fidi ẹ mulẹ pe loootọ niwe-ẹri ti wọn n sọrọ nipa ẹ jẹ ayederu. Tori naa, o ni ile-ẹjọ da ẹjọ ọhun nu.

Ṣaaju ni ẹgbẹ oṣelu APC ati ọmọ ẹgbẹ wọn kan, Ọgbẹni Williams Edobor, ti rawọ ẹbẹ si kootu ọhun lati kede pe iwe-ẹri awuruju ni Gomina Ọbaseki fi ṣọwọ si ajọ eleto idibo INEC nigba to n dije fun ipo gomina, ati pe ko yẹ nipo gomina to wa, ki wọn yẹ aga mọ ọn nidii.

Gomina Ọbaseki ti fesi si idajọ yii, o ni oun kọ loun bori, eto iṣejọba awa-ara-wa lo ṣẹgun, o si dupẹ lọwọ awọn ololufẹ ẹ fun adura ati aduroti wọn.

Leave a Reply