Ile-ẹjọ da ọga agba JAMB tẹlẹ, Dibu Ọjẹrinde, pada sẹwọn lori ẹsun jibiti nla

Faith Adebọla

Gbogbo akitiyan Amofin agba Peter Ọlọrunniṣola lati gba beeli fun onibaara rẹ, Ọgbẹni Dibu Ọjẹrinde, to ti figba kan jẹ ọga agba fun ajọ JAMB ilẹ wa, lo fori ṣanpọn ni kootu lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, niṣe nile-ẹjọ paṣẹ pe ki wọn da baba naa pada sọgba ẹwọn, latari ẹsun kikowojẹ tijọba fi kan an.

Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ati jibiti lẹnu iṣẹ ọba, ICPC (Independent Corrupt Practices and other related offences) lo foju afurasi ọdaran naa bale-ẹjọ giga kan l’Abuja, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, wọn lowo to to biliọnu marun-un ati miliọnu meji naira (#5.2b) lo dawati mọ ọn lọwọ lasiko to fi n tukọ ajọ to n mojuto idanwo aṣewọle si yunifasiti, JAMB.

Ninu iwe ẹsun rẹ ti wọn kọ nọmba FHC/ABJ/CR/97/2021 si, ẹsun mọkandinlogun ni wọn ka si i lẹsẹ, lara ẹsun ọhun ni pe o lọwọ ninu didari owo ijọba gba ibomi-in, titẹ ofin ati ilana owo nina loju, igbim-pọ lati ja ijọba lole, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ninu ọkan lara ẹsun ọhun, wọn lawọn ri i ninu akọsile Alagba Dibu pe ileeṣẹ meji ọtọọtọ ni ọkunrin naa gbeṣẹ fun pe ki wọn bawọn pese pẹnsu (pencil) ati iresa (erazer), ọtalenirinwo o din mẹwaa miliọnu naira (#450m) lo si gbeṣẹ naa jade fun ọkọọkan ileeṣẹ mejeeji ọhun. Wọn lorukọ awọn ileeṣẹ naa ni Double 07 Concept Limited ati Pristine Global Concept Limited, laarin ọdun 2013 si 2014 niṣẹlẹ naa si waye. Ajọ ICPC ni pẹlu gbogbo bawọn ṣe gbọn akọsilẹ ajọ JAMB to, awọn o ri ẹri pe ẹnikẹni pese pẹnsu ati iresa kankan, bẹẹ lawọn o si ri ileeṣẹ to n jẹ orukọ yii mọ.

O ni oriṣiiriṣii iwa jibiti ati ikowojẹ, titi kan fifi anfaani ipo to wa gẹgẹ bii ọga agba ajọ JAMB ko ijọba ataraalu nifa naa waye laarin ọjọ kẹwaa, oṣu kẹrin, ọdun 2012 si ọjọ ki-in-ni, oṣu kẹjọ, ọdun 2016.

Bi wọn ṣe ka awọn ẹsun naa si i leti tan, Ọgbẹni Dibu loun o jẹbi pẹlu alaye.

Lẹyin eyi ni agbẹjọro rẹ, Amofin Ọlọrunniṣhọla, bẹbẹ pe kile-ẹjọ fun onibaara oun ni beeli ko le maa tile waa jẹjọ rẹ, ati ki oun le raaye ṣayẹwo awọn ẹri ti olupẹjọ ko kalẹ lati fi ta ko o, tori awọn iwe ẹsun naa ko tete tẹ oun lọwọ.

Ṣugbọn Agbefọba, Ebenezer Shogunlẹ, ni oun ko fara mọ yiyọnda beeli fun afurasi ọdaran naa, o ni beeli ti ajọ ICPC ti fun un tẹlẹ ko bofin mu, ko si ni i tọna kile-ẹjọ tun fun un niru beeli yii lẹẹkeji.

Adajọ Objora Egwutu ko ro o lẹẹmeji rara to fi wọgi le ibeere fun beeli ọhun, o ni oun o tiẹ fẹẹ gbọ ọrọ nipa beeli bayii, o paṣẹ ki wọn lọọ fi Dibu Ọjẹrinde sahaamọ ọgba ẹwọn titi di ọjọ kẹjọ, Tọsidee, ti igbẹjọ mi-in yoo tun waye, toun yoo si tẹti si ẹbẹ wọn fun beeli ti wọn n beere ọhun.

Leave a Reply