Ile-ẹjọ da Sunday Igboho lare, o ni kawọn DSS san biliọnu lọna ogun Naira fun un

Jọkẹ Amọri

Ile-ẹjọ giga kan to jokoo niluu Ibadan, labẹ idari Adajọ Ladiran Akintọla, ti paṣẹ pe ki ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ilẹ wa, DSS, san biliọnu lọna ogun naira fun ajijagbara ọmọ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ ti gbogbo eeyan mọ si Sundayu Igboho, pẹlu bi wọn ṣe wọle rẹ lọna aitọ, ti wọn ba dukia rẹ jẹ, ti wọn si tun paayan nibẹ lọjọ kin-in-ni, oṣu keje, ọdun yii.

Adajọ Akintọla sọ pe bi wọn ṣe ya wọlẹ ọkunrin naa ko bofin mu, bẹẹ lo sọrọ sileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ yii pe iwa ti wọn hu naa lodi, nitori ibinu ati itara pe Sunday Igboho n ja fun Orileede Oduduwa ti wọn n pe ni Yoruba Nation ni wọn fi kọ lu ile rẹ

Tẹ o ba gbagbe, ọjọje ọdun yii, lawọn ọtelemuyẹ kọ lu ile Sunday Igboho, ti wọn ba ọpọlọpọ dukia jẹ, ti wọn si tun pa meji ninu awọn ọmọ ẹyin rẹ.

Leave a Reply