Ile-ẹjọ da Yayi lọwọ kọ, wọn ni ko ti i le ṣe sẹnetọ l’Ogun

Gbenga Amos, Abẹokuta
Ọrọ ti wọn pe l’owe ti bẹrẹ si i ni aro ninu lori eto idibo abẹle sipo ṣenetọ ti yoo ṣoju awọn eeyan ẹkun idibo Iwọ-Oorun ipinlẹ Ogun, ile-ẹjọ giga kan ti da Ọlamilekan Adeọla tawọn eeyan mọ si Yayi lọwọ kọ, wọn lawọn o tii gba poun lo jawe olubori fun ipo naa ninu ẹgbẹ oṣelu APC.
Ile-ẹjọ giga apapọ kan to fikalẹ si Iṣabọ, niluu Abẹokuta, lo paṣẹ naa lọsan-an ọjọ Aje, Mọnde, ọgbọnjọ, oṣu Karun-un yii.
Awọn olupẹjọ mẹrin kan ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ All Progressives Congress (APC) lagbegbe Yewa, Adebiyi Adeyinka Tajudeen, Ọlajumọkẹ Ibrahim ati Muideen Akintade, ni wọn rawọ ẹbẹ si kootu ọhun pe ko ba awọn so ewe agbejẹẹ mọ Yayi lọwọ.
Wọn ni iwa to lodi sofin patapata, to si tẹ ofin eto idibo ilẹ wa loju ni bi Ọlamilekan Adeọla ṣe loun fẹẹ jade dupo sẹnetọ to maa ṣoju awọn eeyan Iwọ-Oorun Yewa, tori ọkunrin naa ko si ni Yewa, ko si n gbe lagbegbe naa, ohun ti ofin si sọ ni pe ẹni to maa du iru ipo bẹẹ ti gbọdọ maa gbe lagbegbe ọhun fun akoko gigun pato kan.
Wọn tun ni Sẹnetọ Adeọla ki i ṣe ọmọ bibi agbegbe ọhun, ati pe niṣe lo fẹẹ jẹ meji l’Aba Alade, bẹẹ wọn ki i jẹ meji l’Aba Alade, wọn loun lo ṣi n ṣoju awọn eeyan Iwọ-Oorun ipinlẹ Eko lọwọlọwọ nileegbimọ aṣofin agba l’Abuja, oun ni sẹnetọ wọn, ofin si sọ pe o gbọdọ kọkọ kọwe fipo sẹnetọ Eko silẹ ko too le du sẹnetọ ipinlẹ mi-in, wọn lo lodi bo ṣe fẹẹ jẹ sẹnetọ l’Ekoo ati Ogun lẹẹkan naa.
Wọn tun fẹsun kan Yayi pe ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ogun, ko si sorukọ ẹ ninu iwe awọn ọmọ ẹgbẹ ti Iwọ-Oorun Ogun, wọn ni iwa ọyaju ati aiṣedajọ ododo, iwa ẹni ti ko lẹrii-ọkan ni ọkunrin naa fẹẹ hu, ẹtọ awọn eeyan ẹkun idibo naa lo mọ-ọn-mọ fẹẹ tẹ loju mọlẹ, awọn ko si le fara mọ iru ẹ.
Tẹ o ba gbagbe, Yayi ni wọn kede gẹgẹ bii olubori ninu eto idibo abẹle to waye lọjọ Satide, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, eyi ti wọn ṣe ni gbọngan Oronna, n’Ilaro, lati yan ẹni yoo dupo sẹnetọ fun Iwọ-Oorun Yewa lorukọ APC lasiko eto idibo gbogbogboo to n bọ ni 2023.
Sẹnetọ Tolu Ọdẹbiyi lo wa nipo naa lọwọlọwọ, ṣugbọn gbogbo ibo ọọdunrun din mẹfa (294) ti wọn di lọjọ naa, wọn ni ti Yayi ni, Ọdẹbiyi ati awọn oludije meji yooku ko ni ibo ẹyọ kan.
Ṣa, ile-ẹjọ ti ni ki Yayi waa ro arojare tirẹ lori awọn ẹsun ti wọn fi kan an wọnyi, ẹyin igba naa ni wọn yoo paṣẹ boya o bofin mu fun un lati jade dupo l’Ekoo ati Ogun, ati boya bo ṣe kopa ninu eto idibo abẹle naa tọna, ṣugbọn wọn ni titi tidaajọ yoo fi waye lori ẹjọ naa, ko ma ṣe pe ara ẹ ni aṣoju awọn eeyan ẹkun idibo naa rara.

Leave a Reply