Ile-ẹjọ fagi le bi wọn ṣe da APC lọwọ kọ lori apero gbogbogboo wọn

Faith Adebọla

 O jọ pe nnkan ti bẹrẹ si i ṣẹnuure fun ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), lori apero gbogbogboo ti wọn fẹẹ ṣe lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹta yii, pẹlu bile-ẹjọ giga apapọ kan niluu Abuja ṣe wọgi le aṣẹ ti wọn fi da wọn lọwọ kọ tẹlẹ lori apero naa.

Adajọ Bello Kawu lo wọgi le idalọwọkọ naa laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹta yii, o ni ofin ko faaye gba ọmọ ẹgbẹ kan ṣoṣo lati wọ ẹgbẹ rele-ẹjọ tabi bẹbẹ pe ki wọn wọgi le apero gbogbogboo ẹgbẹ oṣelu APC.

Yatọ siyẹn, Adajọ Bello ni idajọ ile-ẹjọ giga ju lọ kan to waye laipẹ yii lori iru ẹjọ bayii ti sọ aṣẹ idalọwọkọ ile-ẹjọ giga naa di otubantẹ.
Ṣe lati ọjọ kejidinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2021, ni ile-ẹjọ giga naa ti paṣẹ fun ẹgbẹ oṣelu APC ati awọn alakooso ẹgbẹ naa lati jawọ ninu eto apero gbogbogboo ti wọn gbero rẹ na, titi tile-ẹjọ naa yoo fi gbọ atotonu olupẹjọ, Ọnarebu Salisu Umoru, to wọ ẹgbẹ naa rele-ẹjọ.

Ko too di asiko yii ni awuyewuye ti n lọ lori apero naa, latari bi igbimọ kiateta ti Aarẹ Muhammadu Buhari yan ninu oṣu kẹfa, ọdun 2020, eyi ti wọn fi Alaaji Mai Mala Buni, Gomina ipinlẹ Yobe, ṣe alaga rẹ, ṣe n sun ọjọ apero gbogbogboo naa siwaju. Ẹẹmẹta ọtọọtọ ni wọn n dajọ, ti ọjọ naa si n yẹ.

Bakan naa ni ọgọọrọ ẹjọ oriṣiiriṣii to wa ni kootu nipa bi akoso ẹgbẹ APC ṣe n lọ si wa lara ohun to n kọ awọn ọmọ ẹgbẹ lominu lori apero yii.

Lọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹta yii, ni ẹgbẹ oṣelu APC gba ile-ẹjọ lọ, ti wọn si bẹbẹ pe kile-ẹjọ bawọn wọgi le aṣẹ ti wọn fi da wọn lọwọ kọ ọhun, wọn ni ẹjọ naa ko lẹsẹ nilẹ.

Amọ, bo tilẹ jẹ pe ilẹ-ẹjọ giga ti wọgi le aṣẹ yii, sibẹ, wọn ni igbẹjọ yoo ṣi tẹsiwaju lori awọn ẹsun mi-in ti olupẹjọ naa ka si awọn alakooso ẹgbẹ lẹsẹ.

Adajọ ti sun igbẹjọ to kan si ọgbọnjọ, oṣu yii.

Leave a Reply