Ile-ẹjọ faini DPO to lu telọ rẹ lalubami n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

 

 

 

Ọga ọlọpaa, iyẹn DPO tẹlẹ, lagọọ ọlọpaa Iyaganku, CSP Alex Sanni Gwazah, ẹni to lu telọ rẹ lálùbami tan, to tun pe e lẹjọ si kootu ti jẹbi bọ ile-ẹjọ, ẹgbẹrun lọna aadọjọ naira (N150), ladajọ ni ko san fun telọ rẹ naa to n jẹ Lukman Adeniyi.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbe e jade nibẹrẹ oṣu kọkanla, ọdun to kọja (2020), ni CSP Gwazah lu telọ rẹ nilukulu, to si tun ti i mọle. Lẹyin naa lo tun pe e lẹjọ si kootu Majisireeti kẹjọ to wa laduugbo Iyaganku, n’Ibadan, o ni kile-ẹjọ ba oun fiya jẹ ẹ nitori ti ko ran aṣọ ti oun gbe fun un daadaa bi oun ṣe fẹ.

Ṣugbọn Onidaajọ Ọlajumọkẹ Akande ti i ṣe adajọ kootu naa da ẹjọ ọhun nu, wọn lẹjọ ọhun ko fi ibikankan nilaari, paapaa nigba ti ọga ọlọpaa to pẹjọ naa ko yọju si kootu rara nigba meji ọtọọtọ ti wọn gbọ ẹjọ naa.

Lẹyin igba naa l’Ọgbẹni Adeniyi funra rẹ gba ile-ẹjọ giga ijọba ipinlẹ Ọyọ to wa laduugbo Ring Road, n’Ibadan, lọ, o ni kile-ẹjọ ba oun gba ẹgbẹrun lọna ọgọta naira (N60,000), owo iṣẹ ti oun ṣe fun ọga ọlọpaa naa, ṣugbọn to kọ̀ lati san an foun.

ALAROYE gbọ pe ọkan ninu awọn onibaara telọ yii lo mu un mọ ọga ọlọpaa teṣan Iyaganku, ti iyẹn si gbe oriṣii aṣọ mejila fun un lati ran lẹẹkan naa.

Ẹgbẹrun lọna ọgọta naira (N60,000) l’Adeniyi beere gẹgẹ bii owo iṣẹ ati owo ti oun yoo fi ra gbogbo ohun eelo ti yoo pari gbogbo aṣọ naa, ti CSP Gwazah si fara mọ ọn.

Ṣugbọn nigba ti baba telọ gbe awọn aṣọ naa lọọ fun ọga DPO ni teṣan rẹ ni Iyaganku lẹyin to pari iṣẹ tan, kaka ki ọga ọlọpaa sanwo iṣẹ baba naa lẹyin to ti gba aṣọ lọwọ ẹ, igbaju olooyi lo ko bo o, o ni ko ran awọn aṣọ naa tẹ oun lọrun, bẹẹ ni ko fun ẹni ẹlẹni lowo iṣẹ to ṣe.

Ṣugbọn lẹyin ti ọkunrin telọ yii ti lọ tan ni ọga ọlọpaa tun fọgbọn tan baba naa wa si teṣan rẹ to si mọle.

Lẹyin ọjọ meji ti baba onibaba lo latimọle lọga ọlọpaa tun gbe e lọ si kootu, to si paṣẹ fun ile-ẹjọ lati tun fiya mi-in jẹ telọ rẹ naa nitori oriṣii aṣọ mejila ọtọọtọ ti oun ra pẹlu ẹgbẹrun mọkanlelọgọsan-an naira (181) lọkunrin naa ran ni irankuran-an, to si ṣe bẹẹ fi oun lowo ṣofo.

Ninu ẹjọ tuntun ti Ọgbẹnu Lukman pe sile-ẹjọ giga yii lo ti ṣalaye pe latigba ti ọrọ yii ti wa ni kootu lọga ọlọpaa naa ti n dukooko mọ oun pe oun (ọga ọlọpaa) yoo tun ti oun (telọ) mọle bi oun ko ba yara gbe ẹjọ naa kuro ni kootu, tabi ki oun yọ ọrọ owo itanran sisan kuro ninu ẹjọ naa.

O ni nitori ẹru ti olujẹjọ naa n da ba oun lo jẹ ki oun ko kuro laduugbo Oke-Bọla, n’Ibadan, ti ṣọọbu oun wa tẹlẹ, ko ma di pe ọkunrin naa yoo pada fijanba ṣe oun.

Ariwo to tẹyin ẹjọ ti telọ yii pe l’ALAROYE gbọ pe o mu ki ileeṣẹ ọlọpaa gbe CSP Gwazah kuro nipo DPO to wa ni teṣan Iyaganku, wọn si sọ ọ di oludari ẹka to n ri si ipe pajawiri ti awọn araalu ba pe si ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa.

Ninu idajọ ẹ to waye lọjọ kẹtalelogun, iyẹn ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, Onidaajọ Rachael Oloyede Ademọla ti ile-ẹjọ giga naa paṣẹ pe ki olujẹjọ san ẹgbẹrun lọna aadọjọ Naira (N150,000) gẹgẹ bii owo itanran fun telọ nitori iya ti ọga ọlọpaa naa fi jẹ ẹ.

Leave a Reply