Monisọla Saka
Ile-ẹjọ to n ri si ọrọ awọn oṣiṣẹ kootu nilẹ Naijiria, NIC, to fikalẹ siluu Abuja, ti pa a laṣẹ lẹyin ọpọlọpọ iwadii ati ayẹwo finnifinni pe ki wọn ṣe afikun si owo-oṣu awọn adajọ atawọn oṣiṣẹ kootu jake-jado orilẹ-ede yii.
Onidaajọ Odatohanmwen Obaseki-Osagie lo gbe idajọ yii kalẹ. O sọ ọ di mimọ pe owo-oṣu awọn adajọ ti wa loju kan rigidi lati bii ọdun mẹrinla.
O ṣalaye pe, pẹlu aduru iṣẹ to wa lọrun awọn oṣiṣẹ ile ẹjọ, wọn o kaaarẹ ọkan lati maa faya ran iṣoro lọ toun towo taṣẹrẹ ati alawansi ti ko to nnkan, eyi ti ile-ẹjọ ṣapejuwe gẹgẹ bii ohun to n ti ni loju ti wọn n fun wọn.
Adajọ tẹsiwaju pe lai si ani-ani, owo-oṣu ti wọn n san fawọn adajọ yii ko pe wọn rara. O ni bi owo Naira ṣe n ja walẹ lojoojumọ n ko ba ọrọ aje awọn adajọ naa.
“Ohun itiju lo jẹ fun orilẹ-ede yii pe pẹlu iṣẹ ati iya tawọn adajọ yii n yi ninu ẹ latari owo ti ko to nnkan ti wọn n san fun wọn, wọn o yee maa ṣe ojuṣe wọn gẹgẹ bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ.
Ohun iyalẹnu lo tun waa jẹ pe awọn to n dajọ gan o ri idajọ ododo”.
Osagie ni awọn adajọ orilẹ-ede yii naa lẹtọọ si ki wọn maa ṣe afikun owo-oṣu wọn loorekoore, ile-ẹjọ NIC, gẹgẹ bi kootu to n ri si ọrọ iṣẹ atawọn oṣiṣẹ ile-ẹjọ ni agbara lati ṣe e ni kannpa fun ijọba apapọ lati tẹle aṣẹ ẹkunwo ti awọn pe fun ọhun.
Nidii eyi, ile ẹjọ pa a laṣẹ pe ki owo-oṣu onidaajọ agba Naijiria goke lọ si miliọnu mẹwaa Naira, nigba ti ti awọn adajọ ile-ẹjọ to ga ju lọ ati ti ile-ẹjọ kotẹmilọrun yoo di miliọnu mẹsan-an Naira.
Bakan naa, ile-ẹjọ paṣẹ pe ki owo-oṣu awọn adajọ ilẹ ẹjọ kotẹmilọrun ati tawọn ile ẹjọ ibilẹ (Customary court) di miliọnu mẹjọ Naira.