Ọlawale Ajao, Ibadan
Ọmọdekunrin ẹni ọdun mejilelogun (22) kan, Matthew Daniel Ogwuche ti dero ẹwọn n’Ibadan.
Yahoo ni wọn lọmọkunrin naa n ṣe, ìyẹn ni pé o n lu awọn eeyan ni jibiti kaakiri lori ẹrọ ayelujara.
Eyi ladajọ ilé-ẹjọ́ gíga ijọba apapọ to wa laduugbo Ring Road, n’Ibadan, Onídàájọ Patrick Ajoku, ṣe sọ ọ ṣẹwọn oṣu meje lọjọ kẹtalelogun, oṣù keji, ọdún 2021, ti i ṣe ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, akẹkọọ ileewe gírámà ni Daniel, ṣugbọn Karlee Grey lorukọ to n lo lori ẹrọ ayélujára gbogbo lati maa fi lu awọn eeyan ni jibiti
Owo ìfà ti ọmọkùnrin ẹni ọdun mejilelogun naa ti bẹrẹ sí í rí lo jẹ ko pa ileewe tị̣̀, to sì dojú kọ jibiti lilu ti wọn n pe ni ‘Yahoo’ loju paali.
Àjọ Economic Aand Financial Crimes Commission, EFCC, lo pe Daniel lẹjọ sí kootu fun ẹsun jibiti lẹyin to lù ẹnikan ni jibiti ojilelẹgbẹta dọ́là o le marun-un (645) eyi to le lẹgbẹrun lọna ojilerugba owo naira ilẹ yii (₦ 246,100).
Lẹyin ti Onídàájọ Ajoku ti sọ ọmọ Ibo yii ṣẹwọn oṣu meje, ile-ẹjọ tun pàṣẹ pé kó dá gbogbo owo to fi ọna eru gba lọwọ ẹni ẹlẹni pada.
Bakan naa ladajọ tun pàṣẹ pé kí awọn agbofinro gba awọn dukia to fi owo jibiti ọhún ra, bíi ẹrọ àgbélétan (lápútọ́ọ́pù) ati ẹrọ ibanisọrọ rẹ kan ti wọn n pe ni Infinix S4, lọwọ ẹ, ki awọn dukia naa sì di tijọba apapọ lọgan.