Ile-ẹjọ ju awọn akẹkọọ mẹsan-an ti wọn fẹsun kan pe wọn fẹẹ pa ọga wọn l’Oṣogbo ṣewọn

Florence Babaṣọla

 

Adajọ ile-ẹjọ Majisreeti kan niluu Oṣogbo ti paṣẹ pe kawọn ọlọpaa lọ fi mẹta ninu awọn akẹkọọ mẹsan-an ti wọn fẹsun kan pe wọn fẹẹ pa ọga ileewe IfẹOluwa Co-Educational Grammar School, Mary Adeoye, sẹwọn.

Awọn mẹfa to ku ni Onidaajọ Ishọla Omiṣade sọ pe ki wọn ko lọ sile ti wọn ti maa n tọ awọn ọmọ kekeke sọna, iyẹn, Juvenile Home, to wa ni Testing Ground, niluu Oṣogbo.

Awọn ọmọ ileewe naa ni wọn wa laarin ogun ọdun si ọdun mẹrindinlogun. Wọn fẹsun kan wọn pe wọn da wahala silẹ ninu ọgba ileewe naa laaarọ ọjọ kẹtadinlogun, oṣu keji, ọdun yii, ti gbogbo awọn akẹkọọ ati olukọ si bẹrẹ si i sare asapajude.

Gẹgẹ bi ọlọpaa ṣe sọ, awọn olujẹjọ naa jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun Aiye Confraternity. Pẹlu oogun abẹnugọngọ, ada, aake atawọn nnkan ija oloro mi-in ni wọn wọ ileewe naa pẹlu erongba lati pa ọga agba naa.

Ẹsun meje ni wọn ka si wọn lẹsẹ, awọn ẹsun naa ni igbimọ-pọ huwa buburu, dida omi alaafia agbegbe ru, kiko awọn nnkan ija oloro rin kaakiri, jijẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun ati didunkooko mọ ẹmi eeyan.

Lẹyin ti wọn sọ pe awọn ko jẹbi ẹsun mejeeji ni agbẹjọro wọn, Ọladipupọ Ọlatunbọsun bẹbẹ fun beeli wọn, ṣugbọn agbẹjọro to wa latileeṣẹ eto idajọ nipinlẹ Ọṣun, Moses Faremi ta ko arọwa yii.

Ninu idajọ Majisreeti Omiṣade, o ni ki wọn lọọ fi awọn ti wọn wa laarin ọdun mejidinlogun si ogun ọdun lara wọn pamọ sọgba ẹwọn ilu Ileṣa, nigba ti awọn tọjọ-ori wọn kere yoo maa lọ sibi ti wọn ti n kọ awọn ọmọde alaigbọran lẹkọọ.

 

Leave a Reply