Ile-ẹjọ loun ko lagbara lati gbọ ẹsun idibo abẹle ẹgbẹ APC l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Ọṣogbo

Ẹjọ ti igun ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun, The Osun Progressive (TOP), pe lati tako idibo abẹnu ẹgbẹ naa to waye lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu keje, ọdun 2022, ni kootu ti taari danu bayii.

Ohun ti awọn TOP gbe siwaju ile-ẹjọ ni pe ki kootu kede pe idibo abẹnu ti awọn igun Ileri Oluwa ṣe ko lẹsẹ nilẹ, ki kootu si kede idibo abala tawọn gẹgẹ bii ojulowo.

Lasiko igbẹjọ, ariyanjiyan wa laarin awọn agbẹjọro Ileri Oluwa ati tawọn TOP lori pe boya ile-ẹjọ lagbara lati da si wahala to ba ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ oṣelu.

Ṣugbọn nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ Emmanuel Ayọọla sọ pe ile-ẹjọ ko lagbara lori ẹsun to ba waye ninu ẹgbẹ oṣelu kan naa.

Ayọọla ṣọ pe irufẹ igbẹjọ bẹẹ ti wa ri nile-ẹjọ to ga ju lọ lorileede yii, ti kootu si sọ pe oun ko ni iru agbara bẹẹ, afi ti ẹjọ bẹẹ ba wa labẹ abala ikẹtadinlaaadọrin ofin orileede yii.

O ni ẹni ti ko ba kopa ninu idibo ko le pe ara rẹ ni oludije gẹgẹ bo ṣe wa ninu ẹjọ ti Marafa pe ẹgbẹ APC, ti ile-ẹjọ si da a nu nigba naa.

Leave a Reply