Ilé-ẹjọ́ ni ki awọn to pa Agboọla kọkọ lọọ gbatẹgun ọsẹ mejila lọgba ẹwọn

Ọlawale Ajao, Ibadan
Awọn afurasi apaayan tó ràn àgbẹ aladaa-nla nni, Ọgbẹni Oluwọle Agboọla, lọ sọrun apapandodo yóò pẹ lẹwọn bíi ọbọ, ọsẹ mejila gbáko nile-ẹjọ sọ pé ki wọn kọkọ fi lọọ gbóòórùn ẹwọn na, ki oun tóo le mọ ijiya to tọ sí wọn gan-an lẹyin ti oun ba gbọ ẹjọ ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan wọn níwájú oun tan.
Awọn olujẹjọ mẹtẹẹta ọhun ni
Dahiru Usman, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn (34); Muhammadu Ahmadu, ẹni ọdun mejilelọgbọn ati (32) Ibrahim Mamuda to jẹ ẹni ogun (20) ọdun.
Tẹ o ba gbagbe, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejidinlọgbọn (28), oṣu kejila, ọdun 2020 yii, lawọn gende ọkunrin mẹfa kan ti wọn mura bii ọmoogun orileede yii ya wọnu oko baba naa to wa lọna Abule Abà-Odò, lagbegbe Mọniya, n’Ibadan, ti wọn si fipa mu un wọ inu igbo lọ niṣeju awọn oṣiṣẹ ẹ.
Ṣaaju ijinigbe ọ̀hún lawọn òṣìṣẹ́ ẹ̀ ti ranṣẹ pè é pé ọkan ninu awọn ẹlẹdẹ to n sìn ti bímọ mẹ́wàá.
Iroyin ayọ yii lo mu àgbẹ̀ aladaa-nla yii sáré gba oko lọ, pẹlu ọmọkùnrin rẹ̀ láti lọọ mojuto nnkan ọsin rẹ naa pẹlu awọn ọmọ tó bí. Kò mọ pé niṣe ni wọn fi iroyin ẹlẹdẹ to bímọ yii tan an fún àwọn ajinigbe mú.
Ni nnkan bíi aago mẹjọ aabọ ọsan lo débẹ. Nibi to si ti n ṣabẹwo sí àwọn oṣiṣẹ ẹ̀ lọkọọkan nibi iṣẹ ọtọọtọ to fi kaluku wọn sì, láwọn ẹrúukú ti wọlé de tibọntibọn, ibọn AK 47 ibọn nla tàwọn ọlọpaa fi n koju awọn ogbologboo adigunjale lọjọ tójú ogun ba le tan poo.
Lẹyin ti awọn ajinigbe ẹlẹni mẹ́fà tí wọn wọ aṣọ soja wọnyi yinbọn sókè láti kó alakọwe to yan iṣẹ àgbẹ̀ láàyò yii láyà jẹ, ni wọn sáré sí ọkunrin naa, ti wọn sì mú un ni pápá mọ́ra jade kuro ninu ọgbà oko nla naa.
Ọjọ keji, lọjọ kọkandinlọgbọn (29), oṣu naa, lawọn ajinigbe pe awọn mọlẹbi ẹ̀ lati jẹ ki wọn mọ pe ọdọ àwọn lẹni wọn wa ati pe mílíọ̀nù lọna àádọta naira (₦50 m) lawọn yóò gba lọwọ wọn ki awọn tóo lè fi í sílẹ.
Ṣugbọn mílíọ̀nù kan ati ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta naira o le mẹ́wàá  (N1.650m) lawọn ẹbi rí ṣà jọ. Lẹyin ọpọlọpọ ẹbẹ lawọn ajinigbe gbowo ọhun bẹẹ lọwọ wọn. Lẹyin naa ni wọn fi àwọn ẹbi baba yii lọkan balẹ pé kí wọn máa retí ẹni wọn nigbakuugba sí asiko naa.
Ṣugbọn lẹyin ti wọn gbowo nla ohun tan ni wọn papa yinbọn papa yín baba naa nibọn pa.
Inu oko ti wọn ti ji olóògbé gbé lawọn ọlọpaa ti bẹrẹ iṣẹ. Ninu ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ti wọn ṣe fawọn oṣiṣẹ inu oko naa náà ni wọn ti gbọ pe eyi to n jẹ Dahiru ninu awọn oṣiṣẹ oloogbe naa ti wọn fi ile ti ọkunrin àgbẹ̀ yii pèsè fawọn oṣiṣẹ ninu ọgbà oko naa ṣe ibugbe kò sí nile lati ọjọ mẹta sẹyin.
Ọjọ ti wọn sanwo fawọn ajinigbe gan-an ni Dahiru kuro ninu ọgbà oko ọga ẹ̀. Eyi lo sí fu àwọn ọlọ́pàá lára ti wọn fi wa ọkunrin ẹni ọdun marundinlogoji (35) naa kan. Nibi kan nitosi Ojú-Irin, ni Bodija n’Ibadan to fara pamọ́ sí ní wọn ti mu un lọjọ kẹta oṣù kin-in ni ọdún yii.
Nigba ti wọn fọrọ gbo ó lẹnu daadaa lo jẹwọ pe oun lọwọ nínú bi awọn Fúlàní ẹgbẹ oun ṣe waa ji ọga oun gbé ati pé aburo oun ti awọn jọ jẹ ọmọ ìyá, ọmọ baba kan naa lo ko àwọn ẹruuku ọ̀hún sòdí waa palẹ ọga oun mọ.
Ìyẹn lawọn agbofinro ṣe tẹsiwaju ninu iwadii wọn ti wọn fi ri Ahmad Muhammadu ati Ibrahim Mamuda mu.
Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ọga agba ọlọpaa ìpínlẹ Ọyọ gbe awọn olujẹjọ naa lọ sí kootu Majisreeti kẹsan-an to wa laduugbo Iyaganku, n’Ibadan, fún ẹsun mẹta ọtọọtọ.
Onidaajo M.A. Amọle-Ajimọtu ti i se adajọ kootu naa ko wulẹ faaye silẹ lati gbọ awijare wọn tó fi sun igbẹjọ naa siwaju di ọjọ kẹ́rindinlọgbọn (26), oṣù karun-un, ọdún 2021 yii, nigba ti ireti wa pe ẹka tó n ri sì eto idajọ ipinlẹ Ọyọ yóò ti gba ile-ẹjọ naa nimọran lati mọ boya awọn afurasi ọdaran naa lẹjọ ọ jẹ tabi bẹẹ kọ.

Leave a Reply