Ile-ẹjọ ni ki Tokẹ Makinwa san miliọnu kan naira fun ọkọ ẹ tẹlẹ

Dada Ajikanje

Miliọnu kan naira nile-ẹjọ giga kan niluu Eko ni ki gbajumọ sọrọsọrọ nni, Tokẹ Makinwa, san fun ọkọ ẹ tẹlẹ, Maje Ayida, lori pe o ba ọkunrin naa lorukọ jẹ.

Ninu idajọ Adajọ Olukayọde Ogunjọbi, lo ti sọ pe Makinwa gbọdọ yọ ohun to kọ nipa ọkọ ẹ tẹlẹ yii kuro ninu iwe to kọ, to pe akọle ẹ ni “On Becoming”.

O lo gbọdọ ṣatunṣe ọhun lori eyi to ku ti ko ti i ta ninu awọn iwe naa laarin ọgbọnjọ.

Leave a Reply