Ile-ẹjọ ni ki wọn yẹgi fun Ọlawale to paayan l’Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

 Ile-ẹjọ giga kan to wa nipinlẹ Ekiti, ti paṣẹ pe ki wọn lọọ so ọkunrin ẹni ọdun mọkanlelọgbọn kan, Ọgbẹni Adebayọ Ọlawale, rọ titi ti ẹmi yoo fi bọ lara rẹ lori ẹsun ipaniyan.

Okunrin ẹni ọdun mọkandinlọgbọn to n gbe ni Eporo-Ekiti, nijọba ibilẹ Emure, ni wọn gbe wa si iwaju Onidaajọ Jubril Aladejana, lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2023, pẹlu ẹsun meji to rọ mọ igbimọ-pọ paayan ati iṣekupaniyan.

Gẹgẹ bi iwe ẹsun ti wọn fi kan an ṣe sọ, wọn ni ọdaran naa ti apejẹ rẹ n jẹ (Wolex), ni oun ati awọn kan ti wọn ko ti i mọ gbimọ pọ lati gba ẹmi lẹnu Ọgbẹni Chukwudi Joseph. Ẹsẹ yii ni ile-ẹjọ naa juwe gẹgẹ bii oun to lodi sofin ipinlẹ Ekiti ti wọn kọ lọdun 2021.

Lakooko to n jẹrii niwaju ile-ẹjọ naa, ẹnikan ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ sọ pe ni deede aago meji ọsan ọjọ naa ni oun ri ọdaran naa ati awọn ọdọ langba meji miiran, ti ọkan lara wọn ṣadede di oloogbe naa to jẹ ọmọ aburo baba oun lọwọ mu lati ẹyin, ti awọn yooku si n la igi mọ ọn lori.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Eyi lo mu mi pariwo, ti mo si gbiyanju lati doola ẹmi oloogbe naa, ṣugbọn niṣe ni ọdaran yii gun oloogbe pẹlu ọbẹ to wa lọwọ rẹ nigbaaya, to si ṣubu lulẹ. Lẹyin ti oloogbe naa ṣubu tan ni ọdaran yii atawọn yooku rẹ sọ pe ti ẹnikẹni ba sun mọ awọn, awọn yoo gun un tọhun pa pẹlu ọbẹ.

“Eyi lo mu ki ẹru ba awọn eeyan, ki awọn to laya si too jade lati waa doola ẹmi oloogbe naa, o ti jade laye. Lẹyin eyi ni mo gbinyanju lati lọọ fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti.”

Lati le fi idi ẹjọ rẹ mulẹ si i, Agbefọba, Arabinrin Ibironkẹ Ọdẹtọla, pe ẹlẹrii mẹfa, bakan naa lo tun fiwe ti awọn ọlọpaa fi gba ohun silẹ lẹnu ọdaran naa lakooko iwadii, ati aworan oloogbe naa gẹgẹ bii ẹri.

Bo tilẹ jẹ pe Ọlawale ti wọn fẹsun kan ko ri ẹlẹrii kankan pe, sibẹ, agbẹjọro rẹ, Ọgbẹni M. A Daramọla, ja fita fita niwaju adajọ lati ri i pe ida ofin ko bẹ onibaara rẹ lori.

Nigba to n sọrọ lori atotonu awọn agbẹjọro mejeeji, Onidaajọ Jubril Aladejana, ṣalaye pe pẹlu bi ọdaran naa atawọn yooku rẹ ṣe la igi mọ oloogbe lori, ti ọkan lara wọn si tun fa ọbẹ yọ, to gun un pa,  eleyii fi han pe wọn mọ-ọn-mọ gbẹmi lẹnu rẹ ni.

Adajọ fi kun un pe ọlọpaa olupẹjọ ti ṣe ohun gbogbo niwaju ile-ẹjọ naa lati fi idi ẹjọ naa mulẹ pe loootọ ni ọdaran naa ṣeku pa oloogbe yii ni Eporo-Ekiti lọjọ kẹwaa, oṣu Kejila, ọdun 2021.

Onidaajọ Aladejana ni, ‘’Ninu ẹsun kin-in-ni to jẹ ẹsun igbimọpọ lati paniyan, ki ọdaran yii maa lọ sẹwọn odun meje, lai ni owo itanran. Ninu ẹsun keji to jẹ ẹsun ipaniyan, ki wọn lọọ so Ọgbẹni Adebayọ Ọlawale kọ soke titi ẹmi yoo fi bọ lẹnu rẹ.”

 

Leave a Reply