Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Adajọ ile-ẹjọ giga kan nipinlẹ Ekiti, Onidaajọ Abiọdun Adesọdun, ti paṣẹ pe ki wọn so awọn ọre mẹta kan rọ titi ti ẹmi yoo fi bọ lara wọn.
Awọn mẹta naa ti wọn jẹ ọrẹ kori-ko-sun ni; Oluwọle Edward, ẹni ọdun mọkandinlaaadọta, Kọlawọle Ojo, ẹni ọdun mọkanlelogoji, ati Kọlawọle Tọpẹ, ẹni ogun ọdun.
Adesọdun sọ pe ẹni kọọkan awọn ọdaran naa jẹbi ẹsun ipaniyan, ole jija ati idigunjale ti ile-ẹjọ naa fi kan wọn.
Ninu ẹsun kin-in-ni, ọdaran kọọkan yoo lọ si ẹwọn ọdun marun-un, bakan naa, ninu ẹsun keji, ikẹrin, ikarun ati ikẹfa, kootu ni ki wọn so ọdaran kọọkan rọ titi ti ẹmi yoo fi bọ lẹnu wọn pẹlu adura pe ki Ọlọrun foriji wọn.
Awọn eeyan naa nile-ẹjọ fi ẹsun igbimọ-pọ lati digunjale ati ipaniyan kan gege bi Agbefọba, Ọgbẹni Julius Ajibare, ṣe sọ, ati gẹgẹ bii imọran to wa lati ileeṣẹ to n gba kootu nimọran. Ọjọ kejila, oṣu kẹrin, ọdun 2017 ni wọn ṣẹ ẹṣẹ yii.
Agbefọba yii sọ pe awọn ọdaran wọnyi gbe ibọn, wọn si da Ọgbẹni Wasiu Ayinde lọna loju ọna to lọ lati ilu Erinmọpe si Ayedun Ekiti, ti wọn si gba ọpọlọpọ miliọnu lọwọ rẹ.
Bakan naa ni awọn mẹta yii tun lọ si oju opopona to lọ lati Ido-Ekiti si Ọtun Ekiti, to tun jade si Ilọfa, nipinlẹ Kwara, nibi ti wọn ti fi ibọn gba owo lọwọ Alhaji Fatai Arowolo.
Ọkan ninu awọn ti awọn janduku yii kọ lu jẹrii nile-ẹjọ pe awọn ọdaran yii gba ẹrọ ilewọ oun lẹyin ti wọn gba gbogbo owo oun tan.
O ṣalaye pe eyi lo fa a ti oun ṣe fi ọrọ naa to ọlọpaa leti, ti wọn si bẹrẹ itọpinpin lati fi panpẹ ofin mu wọn.
Lati fi idi ẹjọ rẹ mulẹ, agbefọba yii pe ẹlẹrii marun-un, bakan naa lo tun ko iwe ti wọn fi gba ọrọ silẹ lẹnu awọn ọdaran naa ni agọ ọlọpaa silẹ. Bẹẹ lo mu iwe ẹsun ti wọn kọ si kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ekiti lati fi ẹsun naa to o leti.