Ile-ẹjọ ni ki wọn yọ ofin kẹrinlelọgọrin eto idibo to di awuyewuye danu

Faith Adebọla

Awuyewuye to ṣi n waye lori ofin eto idibo ti Aarẹ Buhari buwọ lu loṣu Keji, ọdun yii, ti gba ọna mi-in yọ, ile-ẹjọ giga apapọ kan to fikalẹ siluu Umuahia, nipinlẹ Abia, ti paṣẹ pe ki wọn yọ ila kejila, ofin kẹrinlelọgọrin to fa ariyanjiyan naa danu, o ni ki wọn pa a rẹ.

Adajọ Evelyn Anyadike lo paṣẹ bẹẹ laaarọ ọjọ Ẹti, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹta yii, o ni ila kejila naa ko bofin mu, ko lẹsẹ nilẹ, o ta ko ofin ilẹ wa, ko si gbọdọ wa ninu ofin eto idibo rara.

Adajọ naa tun paṣẹ fun Minisita feto idajọ, Amofin agba Abubakar Malami, lati pa ila kejila yii rẹ raurau kuro ninu ofin eto idibo, o ni ki wọn ṣe bẹẹ lẹsẹkẹsẹ ni.

Isọri kejila to fa fa-a-ka-ja-a naa ka pe: “Ẹnikẹni ti wọn ba yan si ipo oṣelu, ipokipo yoowu ko wa, ko le jẹ aṣoju ti yoo dibo tabi ki wọn dibo fun un lasiko apero gbogbogboo tabi lasiko eto idibo abẹle lati yan ọmọ-oye ninu ẹgbẹ oṣelu eyikeyii, afi ti ẹni naa ba kọkọ kọwe fi ipo oṣelu ti wọn yan an si silẹ, o kere tan, aadọrun-un (90) ọjọ ṣaaju irufẹ eto idibo bẹẹ.”

Ninu idajọ rẹ, Adajọ Evelyn sọ pe ila kejila, ofin kẹrinlelọgọrin yii, ko dọgba pẹlu isọri kẹrindinlaaadọrin (66), isọri kẹtadinlaaadọfa (107), isọri kẹtadinlogoje (137) ati isọri kejilelọgọsan-an (182), iwe ofin ilẹ wa, eyi to sọ pe ki ẹnikẹni to ba fẹẹ dupo oṣelu, to si jẹ ẹni ti wọn yan sipo oṣelu tẹlẹ, ki tọhun kọwe fipo silẹ, o kere tan, ọgbọn ọjọ ṣaaju eto idibo bẹẹ.

Adajọ naa ni ofin eyikeyii mi-in to ba fi gbedeke ọjọ to yatọ si eyi ti ofin apapọ ilẹ wa fi lelẹ, iru ofin bẹẹ o ṣee gbara le, ko si gbọdọ duro, ki wọn wọgi le e, ki wọn si pa a rẹ.

Ṣaaju ni ẹgbẹ oṣelu PDP ti rọ ile-ẹjọ naa lati da awọn aṣofin apapọ ilẹ wa lọwọ kọ lori atunṣe tuntun ti Buhari loun fẹ ki wọn ṣe si ofin eto idibo ọhun, lori ofin kẹrinlegọgọrin naa.

Ọsẹ to kọja lawọn aṣofin apapọ da ibeere fun atunṣe ti Buhari fi ṣọwọ si wọn nu bii omi iṣanwọ, wọn ni ẹjọ nipa ofin naa ṣi n lọ lọwọ nile-ẹjọ, afi kẹjọ naa kọkọ pari na.

Lọjọ Tọsidee yii ni Abubakar Malami sọ fawọn oniroyin pe afaimọ nijọba apapọ o ni i kọri sile-ẹjọ lati beere fun atunṣe si ila kejila to di awuyewuye yii, ṣugbọn ni bayii, o jọ pe ibi ti wọn fẹẹ gbin igi si, obi ti lalẹ hu nibẹ lọrọ naa ja si bayii.

Leave a Reply