Ilé-ẹjọ́ rọ Alájáàwà tilu Àjáàwà loye, wọn lọna eru lo gba depo ọba

Ọlawale Ajao, Ibadan

 

Ile-ẹjọ giga tipinlẹ Ọyọ ti pàṣẹ pé ki Alájáàwà tilu Àjáààwà, ni ipinlẹ Ọyọ, Ọba Thompson Oyetunji, kuro lori àpèrè ọba.

Lọjọ kọkànlá, oṣù kẹta, ọdun 2020, nijọba ipinlẹ Ọyọ fi Ọmọọba Oyetunji jọba ilu Ajaawa. Ṣugbọn lọjọ Ajé, Mọnde, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣù kejì, ọdun 2021 yii, l’Onídàájọ Sherifat Adéyẹmí paṣẹ pé kí ìjọba gba ọpa àṣẹ àti ìwé ẹri ti wọn fún ùn gẹgẹ bíi ọba kuro lọwọ ẹ̀ kíá.

Awọn to du oye ọba Àjáàwà, Ọmọọba

Azeez Oyebunmi ati Ọmọọba Kamorudeen Salami, lati idile Olumọle, ni wọn pẹjọ ta ko iyansipo Ọmọọba Oyetunji sipo ọba

Lara awọn ti wọn tun pe lẹjọ, ti wọn sì jẹ olujẹjọ nínú ẹjọ ọ̀hún ni Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, kọmiṣanna feto oye jijẹ ati ọrọ ìjọba ibilẹ atawọn mi-in.

Wọn ní kijọba rọ ẹni tí wọn fi jọba naa loye nitori ọna eru ni wọn gbà fi í síbẹ̀.

Pẹlu bo ṣe jẹ pe igbẹjọ ṣẹṣẹ bẹrẹ lori ọrọ ipo oba Ajaawa ni, ile-ẹjọ ti rọ baba naa lati yee maa pera ẹ̀ lÁlájáàwà tilu Àjáàwà titi

ti oun yóò fi gbe idajọ kalẹ lori ẹjọ náà.

O waa sun igbẹjọ mi-in sí ọjọ kẹrindinlogun, oṣu yìí.

Lẹyin tile-ẹjọ ti ṣe ohun tí wọn n fẹ, Amofin Orodiran ti i ṣe agbẹjọro olupẹjọ, kan saara sí adajọ kootu naa, o ni àṣẹ ododo ti adajọ pa yii ni yóò jẹ kí awọn eeyan tubọ n’igbagbọ ninu ẹka eto idajọ orileede yii.

 

Leave a Reply