Faith Adebọla, Eko
O kere tan, ọgbọn ọjọ, ni Chidinma Ojukwu atawọn afurasi ọdaran ti wọn mọ nipa iku Ọgbẹni Usifo Atanga, ọga agba ileeṣẹ tẹlifiṣan Super TV, yoo fi maa gbatẹgun lọgba ẹwọn Kirikiri, l’Ekoo, ki igbẹjọ lori ẹsun iṣikapaniyan ti wọn fi kan wọn too tẹsiwaju.
Adajọ ile-ẹjọ Majisreeti to fikalẹ si Yaba, Majisreeti Agba Adeọla Adedayọ, lo paṣẹ naa lọjọ Aje, Mọnde yii, nigba ti wọn foju awọn afurasi ọdaran naa bale-ẹjọ.
Ninu alaye ti agbefọba Cyril Ejiofor ṣe niwaju adajọ ni kootu ọhun, o ni oun rọ ile-ẹjọ naa pe ki wọn ṣi fi Chidinma ati ekeji rẹ, Adedapọ Ojukwu, sahaamọ na, ki ileeṣẹ ọlọpaa le raaye fikun lukun pẹlu ajọ to n gba awọn adajọ nimọran, DPP, lati pese itọsọna ati amọran to yẹ lori ẹjọ wọn.
Darẹkitọ DPP, Ọmọwee Babajide Martins, toun naa wa ni kootu ọhun sọ pe wọn o ti i fi awọn iwe ẹsun to kun rẹrẹ lori ẹjọ yii ṣọwọ sawọn, afi tawọn ba si ri isọfunni to yẹ gba lawọn too le pese amọran bo ṣe yẹ. Nitori bẹẹ, oun o ta ko ẹbẹ ti agbefọba bẹ kootu naa, oun fara mọ ọn.
Ẹsun ti wọn fi kan Chidinma ati Adedapọ ni pe wọn mọ-ọn-mọ ṣeku pa Oloogbe Atanga lọjọ kẹtalelogun, oṣu kẹfa, ọdun yii, sinu otẹẹli kan lagbegbe Lẹkki, toun ati Chidinma ti jọ n gbadun ara wọn fun ọjọ mẹta ṣaaju.
Tẹ o ba gbagbe, nigba tawọn ọlọpaa ṣafihan afurasi ọdaran naa, Chidinma, lọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹfa, akẹkọọ Fasiti Eko yii jẹwọ fawọn oniroyin pe loootọ ni, oun loun gun baba alaaanu oun, Atanga, lọbẹ pa, nigba to fẹẹ ba oun laṣepọ toun o si gba fun un, tori ibasun tawọn ti n ṣe bọ ti jẹ ko rẹ oun, ṣugbọn ọkunrin naa ko fẹẹ gba, gẹgẹ bo ṣe wi.
O tun jẹwọ pe oun ati oloogbe naa lawọn ti jọ n fa egboogi oloro loriṣiiriṣii kiṣẹlẹ yii too waye, lẹyin toun si gun un lọbẹ pa tan loun lọọ fi kaadi ATM gba owo jade ninu akaunti oloogbe naa, ti oun si ba ẹsẹ oun sọrọ, kawọn ọlọpaa too waa mu oun nile awọn obi oun ni Surulere.
Ṣugbọn laarin asiko ti Chidinma fi wa lahaamọ awọn ọtẹlẹmuyẹ ti wọn n ṣewadii lori ọrọ yii ni Panti, wọn lo tun yi ọrọ pada fawọn oniroyin kan ti wọn lọọ bi i leere, o ni oun kọ loun gun oloogbe naa lọbẹ, awọn kan ti pa a silẹ koun too wọ yara naa, awọn ti wọn si pa a naa ni wọn da yara ọhun ru, ti wọn sa lọ, koun too de lati ibi toun ti lọọ ra egboogi oloro tawọn fẹẹ fi gbadun ara awọn.
Ṣa, Adajọ Adedayọ ti paṣẹ pe ki wọn lọọ fi Chidinma ati ẹni keji ẹ sahaamọ ọgba ẹwọn fun ọgbọn ọjọ, gẹgẹ bii ibeere agbefọba.
Ọjọ karun-un, oṣu kẹsan-an ni igbẹjọ yoo bẹrẹ ni pẹrẹwu.