Ile-ẹjọ ti da Rọpo, iyawo Sunday Igboho, silẹ o

Lẹyin ti ile-ẹjọ giga, Cour De’appal De Cotonou, ti ilu Kutọnu ni orilẹ-ede Bennẹ ti fi wakati mẹfa jokoo lati gbọ ẹjọ Oloye Sunday Adeyẹmọ, ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho, ile ẹjọ naa ti paṣẹ pe ki wọn tu iyawo rẹ, Rọpo Adeyemọ, silẹ kiakia ko maa lọ.

Obinrin naa ni wọn jọ mu pẹlu ọkọ rẹ lalẹ Ọjọ Aje, Mọnde, to kọja lọ, ti wọn si ti wọn mọle. Ṣugbọn nigba ti awọn adajọ ti wọn n gbọ ẹjọ yi yẹ ọrọ obinrin naa wo, wọn ni oun ko lẹṣẹ kankan, ko si si idi ti wọn fi gbọdọ ti i mọle rara, ẹsẹkẹsẹ ni wọn si ti paṣẹ ki wọn yọ ọ jade. Ṣugbọn wọn da ọkọ rẹ pada satimọle.

Bo tilẹ jẹ pe oni yii ti i ṣe ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtalelogun oṣu keje ọdun 2021, ni ireti ti wa tẹlẹ pe wọn yoo gbọ ẹjo ọkunrin ajijagbara ọmọ Yorub naa, sibẹ awọn kan n sọ ni Kutọnu pe o ṣẹe ṣe ki awọn adajọ ma ṣiṣẹ loni-in, ṣugbọn a ko ti i ri eyi fi idi rẹ mulẹ daadaa.

Ẹsun meji ọtọọtọ lo wa niwaju Igboho, ṣugbọn eyi to jẹ ẹsun akọkọ ni wẹn fẹẹ yanju na, iyẹn naa si ni eyi to jẹ mo ti iwe irinna to fẹẹ fi ba orilẹ-ede wọn kọja lọ siluu oyinbo, ti wọn ba yanju eyi tan ni wọn yoo ṣẹṣẹ gbọ ẹjọ boya ijọba Naijiria lẹtọọ lati gba Sunday Igboho lọwọ awọn ara Bẹnnẹ, ki wọn si fi tipatipa da pada wa sile.

Nigba ti yoo ba fi di ọwọ iyalẹta, ibi ti ọrọ naa yoo ba gba lọ, awọn oniroyin wa yoo ti mu un waa fun wa.

 

Leave a Reply