Ile-ẹjọ ti fun Baba Ijẹṣa ni beeli

Faith Adebọla

Ileeẹjọ to n ri si awọn ẹsun to ba ṣe pataki ti wọn n pe ni Special Offence Court to wa niluu Ikẹja, nipinlẹ Eko, ti gba beeli Baba Ijẹṣa, wọn ni ko tile waa maa jẹjọ ẹsun ṣiṣe ọmọde baṣubaṣu ti wọn fi kan an.

Nigba ti Adajọ Toyin Taiwo to  gbọ ẹjọ naa n gbe ipinnu rẹ kalẹ, o ni oun ṣetan lati fun Baba Ijẹṣa ni beeli, ṣugbọn awọn ohun to rọ mọ gbigba beeli ọhun niyi gẹgẹ bi Adajọ Toyin ṣe sọ.

Akọkọ ni pe o gbọdọ fa ẹlẹrii meji kalẹ. Bakan naa ni agbẹjọro rẹ gbọdọ duro fun un. Yatọ si eleyii, ọkan ninu awọn mọlẹbi rẹ gbọdọ wa laarin awọn oniduuro yii, ti wọn si gbọdọ ni miliọnu meji, o kere tan, lakaunti wọn. Bẹẹ ni wọn gbọdọ ni iwe-ẹri owo-ori ọdun mẹta ti wọn ti san sipinlẹ Eko.

Olori awọn lọọya to gbẹjọro fun Baba Ijẹṣa ni Babatunde Ọgala, oun naa wa lara awọn ti wọn duro fun un.

 

Ọjọ kẹrindinlọgbọn, ketadinlọgbọn ati ikejidinlọgbọn, oṣu to n bọ, ni wọn sun igbẹjọ oṣere naa si ti yoo tun fara han nile-ẹjọ.

Leave a Reply