Ile-ẹjọ ti gba beeli awọn ọmọlẹyin Sunday Igboho mejeejila

Faith Adebọla

Ile-ẹjọ giga to wa niluu Abuja ti gba oniduuro awọn ọmọlẹyin Sunday Adeyẹmọ ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho ti wọn ko lasiko ti wọn lọọ ṣakọlu si  ọkunrin naa ni ọjọ kin-in-ni, oṣu keje, ọdun yii, nile rẹ to wa ni Soka, niluu Ibadan.

Miliọnu marun-un naira ni wọn fi gba beeli awọn mẹjọ ninu wọn, pẹlu oniduuro meji meji to n gbe niluu Abuja. Nigba ti wọn gba beeli awọn mẹrin to ku ti ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ni awọn ko ni i fi silẹ nitori pe awọn fura si wọn pe wọn n ko nnkan ija oloro, wọn si tun jẹ ọdaran ni miliọnu mẹwaa naira ẹni kọọkan.

Awọn oniduuro yii gbọdọ maa gbe ilu Abuja, ki ọkan ninu wọn jẹ oṣiṣẹ ijọba to wa ni ipele kejila soke. Bakan naa ni awọn eeyan naa gbọdọ pese iwe igbaniṣiṣẹ wọn ati iwe ti wọn fi sanwo-ori ni ọdun mẹta sẹyin.

Awọn mẹrin ti ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ lawọn ko ni i fi silẹ, ṣugbọn ti adajọ pada paṣẹ pe ki wọn gba beeli wọn ni:Amudat Babatrunde, Ọkọyẹmi Tajudeen, Abideen Shittu ati Jamiu Noah Oyetunji

Ninu idajọ rẹ, Onidaajọ Egwuatu sọ pe adajọ ni anfaani labẹ ofin lati lo ọpọlọ rẹ lori ẹjọ to ba jẹ mọ bẹẹ lati fun awọn eeyan yii ni beeli.

Leave a Reply