Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ile-ẹjọ Magistreeti kan to wa niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, ti sọ pe ki ọkunrin agbẹ kan, Mufutau Adekola, maa lọọ gbatẹgun lọgba ẹwọn Oke-Kura, niluu Ilọrin, fẹsun pe o ṣeku pa iya rẹ, Rafatu ati aburo rẹ, Mukaila, lasiko ti wọn n sun lọwọ ni ilu Oke-Ode, nijọba ibilẹ Ifẹlodun, nipinlẹ Kwara.
Agbefọba, Insipẹkitọ Fọlọrunshọ Zacheaus, lo wọ arakunrin agbẹ naa, Adekọla, lọ siwaju ile-ẹjọ, to si sọ pe lasiko ti iya rẹ, Rafatu, ati aburo rẹ, Mukaila, n sun lọwọ lo lọọ ṣe akọlu si wọn, ti awọn mejeeji si dero ọrun. Iwa ọdaran ni eyi, o si ta ko abala okoolenigba ati ẹyọ kan ( 221) ninu iwe ofin ilẹ wa, fun idi eyi, o di dandan ko jiya ẹsẹ rẹ.
Onidaajọ Ibrahim Dasuki ti waa paṣẹ pe ki wọn fi Adekọla si ọgba ẹwọn Oke-Kura titi ti wọn yoo fi pari gbogbo iwadii lori iṣẹlẹ ọhun.
Lẹyin eyi lo sun igbẹjọ miiran si ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun yii.