Faith Adebọla
Ile-ẹjọ giga kan to jokoo niluu Inadan, nipinlẹ Ọyọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii ti pase pe ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ, iyẹn DSS, ati adajọ agba nilẹ wa, ko laṣẹ lati pe Sunday Igboho ni ọdaran, wọn ko laṣẹ lati gbẹsẹ-le owo to wa ni akunti rẹ, bẹẹ ni wọn ko laṣẹ lati fọwọ ofin kankan mu un.
Idajọ yii waye pẹlu ẹjọ ti agbẹjọro rẹ, Yọmi Aliu pe lori ọrọ naa. Lẹyin igbẹjọ yii ni Onidaajọ Akinọla sọ pe wọn o gbọdọ dẹruba a, wọn o gbọdọ halẹ mọ ọn, wọn o gbọdọ ti i mọle, bẹẹ ni wọn ko gbọdọ pa a, bẹẹ ni wọn ko gbọdọ gbẹsẹ le oṣunwọn owo rẹ ni banki.
Wọn ni o lẹtọọ ati aṣẹ lati rin, ko si yan fanda gẹgẹ bii ọmọ orileede yii, wọn ko si gbọdọ ṣakọlu kankan si ile rẹ.
Gbogbo aọn ti won gbọ idajọ yii ni wọn fo fayọ, ti wọn si n kan saara si ileeṣẹ eto idajọ fun idajọ aiṣegbe lẹyin ẹnikan yii.
Idajọ yii waye pẹlu bi agbẹjọro rẹ, Alli ṣe gba ile-ẹjọ lọ lẹyin ti wọn ṣakọlu si ile rẹ niluu Ibadan lọjọ ki-in-ni, oṣu keje ọdun yii, ti wọn si ba ọpọlọpọ nnkan jẹ. Biliọnu marun-un naira lo beere fun lori iwa ti ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ hu yii.