Ile-ẹjọ ti tu mẹjọ ninu awọn ọmọọṣẹ Sunday Igboho silẹ

Jọke Amọri

Ile-ẹjọ ti gba beeli mẹjọ ninu awọn eeyan ti wọn ko nile Ọloye Sunday Adeyẹmọ ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho.

Ọsan ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni agbẹjọro wọn, Pẹlumi Ọlajẹngbesi, sọ pe awọn ọtẹlẹmuyẹ ti tu mẹjọ ninu awọn eeyan naa silẹ. Awọn ti wọn gba ominira naa ni:Abdullateef Ọnaọlapọ, Tajudeen Ẹrinoye, Diẹkọla Jubril, Ayọbami Doland, Uthman Adelabu, Oluwafẹmi Kunle, Raji Kazeem ati Bamidele Sunday.

Ọlajẹngbesi ni iṣẹ ti n lọ lati ri i pe awọn mẹrin to ku naa gba ominira. Ati pe o pẹ tan, titi ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, awọn yoo gba wọn jade.

Leave a Reply