Ile-ẹjọ to ga ju lọ buwọ lu lilo hijaabu lawọn ileewe nipinlẹ Eko

Monisọla Saka

Lẹyin ọpọlọpọ ọdun ti wọn ti n pe fun atunṣe si ofin tijọba ipinlẹ Eko gbe jade lori ilo hijaabu, ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ Naijiria ti faaye gba awọn akẹkọọ-binrin ileewe ijọba kaakiri ipinlẹ Eko lati maa bori wọn pẹlu hijaabu.
L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, nile-ẹjọ giga ọhun gba awọn akẹkọọ-binrin Musulumi laaye lati maa lo hijaabu ninu ileewe.
Adajọ fagi le ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun tijọba ipinlẹ Eko pe, to si duro lori pe ẹjọ ti ile ẹjọ Ko-tẹ-mi-lọrun (Court of Appeal) ọhun da ta ko ẹtọ awọn akẹkọọ-binrin Musulumi nipinlẹ naa.
Lara awọn adajọ to wa nikalẹ ni, Onidaajọ Olukayọde Ariwoọla, Onidaajọ Kudirat Kekere-Ẹkun, Onidaajọ John Inyang Okoro, Onidaajọ Uwani Aji, Onidaajọ Mohammed Garba, Onidaajọ Tijjani Abubakar ati Onidaajọ Emmanuel Agim.

Ile-ẹjọ yii sọ pe ofin ti wọn fi de lilo hijaabu tẹlẹ ta ko ẹtọ awọn akẹkọọ Musulumi si ero, ẹri ọkan, ẹsin ati iwa ọmọluabi ati ẹtọ lati ma ṣe huwa ẹlẹyamẹya si ni gẹgẹ bo ṣe wa ninu iwe ofin ilẹ Naijiria tọdun 1999.
Ijọba ipinlẹ Eko ti gbẹsẹ le lilo hijaabu tẹlẹtẹlẹ pe ko si lara aṣọ ileewe ti wọn gba awọn akẹkọọ laaye lati maa lo.
Bi ijọba Eko ṣe ti fagi le lilo hijaabu fawọn akẹkọọ-binrin yii lawọn ẹgbẹ akẹkọọ Musulumi ti pẹjọ lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2015, ti wọn si pe fun atunṣe gẹgẹ bi wọn ṣe sọ fun ile-ẹjọ pe igbesẹ ijọba n ta ko ẹtọ awọn si ero, ẹsin ati ti eto ẹkọ.

Leave a Reply