Ile-ẹjọ to ga ju lọ da ẹjọ Buhari ti Malami pe ta ko ofin eto idibo nu

Faith Adebọla

Ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa ti wọgi le ẹjọ ti Aarẹ Muhammadu Buhari ati Minisita feto idajọ, Amofin agba Abubakar Malami, pe ta ko ofin eto idibo nu, wọn ni ẹjọ naa ko lẹsẹ nilẹ.
Ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni Buhari ati Malami gba ile-ẹjọ to ga ju lọ lọ, wọn ni ki wọn da si awuyewuye lori ofin to wa ni isọri kẹrinlelọgọrin, ila kejila, iwe ofin eto idibo ilẹ wa, ti Buhari ṣẹṣẹ buwọ lu loṣu Keji, ọdun yii. Ileegbimọ aṣofin ilẹ wa ati ajọ eleto idibo apapọ, INEC ni olujẹjọ.
Labẹ isọri naa ni ofin ti ka a leewọ pe gbogbo awọn ti wọn ba yan sipo oṣelu, yatọ si awọn ti araalu dibo fun ni taara, wọn ko ni anfaani lati dije fun ipo lasiko ti ẹgbẹ oṣelu wọn ba n yan ijoye ẹgbẹ, wọn o le dibo fun-un-yan, eeyan o si le dibo fun wọn, bẹẹ ni wọn ko le kopa ninu yiyan ẹni ti ẹgbẹ yoo fa kalẹ fun ipo oṣelu lasiko eto idibo gbogbogboo.
Ofin yii ti da awuyewuye silẹ, latari bi Aarẹ Buhari ṣe sọ lọjọ to n buwọ lu ofin eto idibo naa, o ni isọri yii ko tẹ oun lọrun, tori o gbegi dina ẹtọ awọn eeyan kan, o si loun maa fẹ kawọn aṣofin naa lọọ pada yiri ofin ọhun wo, ki wọn pa a rẹ tabi tun un kọ.
Ọsẹ meji lẹyin eyi ni ile-ẹjọ giga ilu Umahia, nipinlẹ Abia, paṣẹ pe ki wọn wọgi le ofin naa, o lo ta ko iwe ofin ilẹ wa. Gẹrẹ ti idajọ yii waye ni Abubakar Malami ti loun fara mọ idajọ naa, ijọba apapọ maa ṣe gẹgẹ bi ile-ẹjọ ti paṣẹ.
Ṣugbọn ọrọ yii di awuyewuye nla, awọn aṣofin apapọ lawọn o fara mọ aṣẹ ile-ẹjọ yii, wọn ni idajọ naa ti ya ju, nitori ko sẹni to gbọ igba ti wọn jokoo ẹjọ, wọ kan dajọ naa paapaapa ni. Awọn to yẹ ko mọ si i paapaa ko mọ rara. Nitori wọn o pe awọn lati ṣalaye bi ofin ti wọn n sọrọ nipa ẹ yii ṣe jẹ, wọn si tun kilọ pe Malami ko lagbara labẹ ofin lati wọgi le ofin tawọn aṣofin ṣe, wọn lawọn tawọn ṣe ofin nikan lawọn le pa a rẹ to ba yẹ bẹẹ.
Eyi lo mu kawọn aṣofin naa pe Buhari ati Malami lẹjọ sile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun l’Abuja, wọn ni ki wọn ba wọn wọgi le idajọ ile-ẹjọ giga ti Umuahia yẹn.
Nigba ti ilẹ-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun maa gbe idajọ tirẹ kalẹ, niṣe lọrọ naa tubọ ta koko, kootu naa sọ pe idajọ ile-ẹjọ Umuahia ko tọna, tori olupẹjọ ko laṣẹ lati pe ẹjọ, ko si dara bi wọn ko ṣe fi ọrọ lọ ileegbimọ aṣofin agba, tori naa, wọn wọgi le idajọ ọhun. Lọwọ keji, kootu naa ni oun gba pe ofin ti wọn n sọrọ nipa ẹ yii ko bọ si i, wọn ni isọri naa ta ko iwe ofin ilẹ wa.
Eyi lo mu Buhari ati Malami kọri sile-ẹjọ to ga ju lọ. Owurọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹfa yii, ni wọn gbe idajọ wọn kalẹ. Igbimọ adajọ meje to bojuto ẹjọ naa fohun ṣọkan pe niwọn igba ti Aarẹ Buhari ti le buwọ lu ofin eto idibo naa lodidi, ko tọna fun oun tabi minisita rẹ lati tun pada ṣaroye lori apa kan ofin ọhun, wọn ni aarẹ ko le maa lọ siwaju sẹyin lori ofin to ti buwọ lu.
Onidaajọ Emmanuel Agim, to gbe idajọ naa kalẹ lorukọ awọn akẹgbẹ rẹ, ni fifi akoko ile-ẹjọ ṣofo lo jẹ lati pe iru ẹjọ yii, wọn ni awọn o le ṣepinnu kankan lori boya ofin naa dara tabi ko dara.
Ilẹ-ẹjọ naa tun ṣalaye pe ko tọna fun ileeṣẹ Aarẹ lati beere lọwọ awọn aṣofin tabi ile-ẹjọ boya ofin ti Aarẹ ti buwọ lu dara tabi ko dara, ko si tọna lati da ofin naa pada fun atunyẹwo tabi atunṣe.
“Ko si ibikan ninu ofin ilẹ wa to fun aarẹ lagbara lori iṣẹ awọn aṣofin, aarẹ o si lẹtọọ lati maa ṣe ariwisi tabi atupalẹ ofin tawọn aṣofin ba ṣe.”

Leave a Reply