Ile-ẹjọ to ga ju lọ da Lawan lare, wọn loun loludije funpo sẹnetọ tawọn faṣẹ si

Faith Adebọla

Ilẹkẹ ma ja sile, ma ja sita, ibi kan nilẹkẹ maa ja si, beeyan meji ba si n fa abẹ mọ ara wọn lọwọ, ẹnikan ni abẹ yoo pa lọwọ. Ọrọ yii lo ṣe rẹgi pẹlu idajọ ile-ẹjọ giga ju lọ nilẹ wa ti wọn gbe kalẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹfa, oṣu Keji yii, lori ariyanjiyan nipa ẹni ti yoo ṣoju awọn eeyan ẹkun idibo Ariwa Yobe, nileegbimọ aṣofin agba, iyẹn sẹneeti, lorukọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), ninu eto idibo to ku ọsẹ mẹta pere yii. Ile-ẹjọ naa ti pa ilu mọ Ọgbẹni Bashir Machina to ti n polongo ibo latọjọ yii nidii, wọn ni Olori awọn aṣofin, Sẹnetọ Ahmad Lawan, ni ifa awọn fọre fun.

Bakan naa ni ile-ẹjọ giga ju lọ ọhun tun wọgi le idajọ ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun, eyi to ti da Machina lare, ti eyi si ṣe rẹgi pẹlu idajọ ti ile-ẹjọ giga kan ti kọkọ gbe kalẹ lori ariyanjiyan naa.

Ile-ẹjọ giga ju lọ ni awọn aṣiṣe kan ti ko tọna, ti ko si yẹ ko waye, ṣẹlẹ ninu igbẹjọ ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun, wọn ni ọkan lara ẹsun ti olujẹjọ,  iyẹn Machina, fi kan olupẹjọ, ti i ṣe ẹgbẹ oṣelu APC, ni pe APC lu oun ni jibiti, wọn yọ orukọ oun kuro, wọn fi ti Lawan rọpo ẹ, bẹẹ oun loun jawe olubori nibi eto idibo abẹle ti wọn fi yan oludije, eyi ti Lawan ko kopa ninu ẹ rara, tori olori awọn aṣofin naa ti lọọ dije funpo aarẹ ninu eto idibo abẹle mi-in nigba yẹn.

Wọn niru ẹsun iwa jibiti bẹẹ ko yẹ lohun ti ile-ẹjọ eyikeyii yoo foju fo da, ti wọn yoo fi ẹtẹ silẹ pa lapalapa, niṣe lo yẹ ki wọn tuṣu desalẹ ikoko ẹsun yẹn ni, ki wọn si pe awọn ẹlẹrii lati fidi ododo mulẹ, kikọ ti wọn kọ lati ṣe bẹẹ lo mu kawọn da idajọ wọn nu bii omi iṣanwọ, ti ẹjọ naa fi waa pada ṣe Lawan loore.

Awọn mẹta ninu igbimọ onidaajọ ẹlẹni marun-un tile-ẹjọ giga ju lọ naa ni wọn fẹnu ko pe ki Machina kuro nipo oludije, ki Lawan si bọ saaye ẹ, bẹẹ ni wọn paṣẹ fun ajọ eleto idibo ilẹ wa, INEC lati, fi orukọ Lawan rọpo Machina lẹyẹ-o-sọka.

Ẹ oo ranti pe oṣu Karun-un, ọdun 2022, to kọja ni wọn kede pe Bashir Machina bori lai si alatako nibi eto idibo abẹle APC lẹkun idibo sẹneeti Ariwa Yobe. Ko pẹ lẹyin naa ti Ahmed Lawan fidi-rẹmi ninu idije funpo aarẹ, ti wọn kede Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu gẹgẹ bii oludije, ni ẹgbẹ APC ba tun ṣeto idibo abẹle bookẹlẹ kan lọtọ, nibi ti wọn ti ni Lawan lo yege, wọn ni ki Machina juwọ silẹ fun un, n lọkunrin naa ba faake kọri, o si gba ile-ẹjọ lọ.

Ninu oṣu Kẹsan-an, ọdun 2022, nile-ẹjọ giga kan to wa niluu Damaturu kede rẹ pe oun ni oludije funpo sẹnetọ gidi, wọn ni ki INEC forukọ ẹ silẹ.

Lawan ni oun ko gba, lo ba pẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun. Oṣu kẹwaa, ọdun naa, ni idajọ ko-tẹ-mi-lọrun waye, Machina yii kan naa si ni wọn mu, wọn ni ki Lawan lọọ wabikan jokoo si.

Nibi yii lọrọ de ti Lawan fi loun o ṣẹjọ mọ, oun ti gba f’Ọlọrun, ati pe ẹnikan ki i jẹ kilẹ o fẹ, o loun fara mọ ọn ki Machina lọ.

Amọ ẹgbẹ oṣelu wọn, APC ni awọn ṣi fẹ kẹjọ naa de ile-ẹjọ giga ju lọ, eyi ti idajọ rẹ waye lọjọ Mọnde yii, ti idajọ naa si dẹrin-in pẹẹkẹ Lawan, gẹgẹ bii oludije ti wọn fọwọ si.

Leave a Reply