Ile-ẹjọ to n gbọ awuyewuye idibo ni Jẹgẹdẹ lẹtọọ lati ṣayẹwo awọn ohun eelo idibo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ 

Ile-ẹjọ to n gbọ awuyewuye to ba su yọ ninu eto idibo ti fun oludije ẹgbẹ oṣelu PDP, Eyitayọ Jẹgẹdẹ, laaye ati ṣayẹwo gbogbo awọn ohun eelo ti wọn lo lasiko eto idibo gomina to waye lọjọ kẹwaa, oṣu to kọja.

Alaga igbimọ olugbẹjọ ẹlẹni mẹta naa, Onidaajọ Umar Abubakar, lo pasẹ yii lasiko ijokoo wọn akọkọ to waye lọjọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọse yii, niluu Akurẹ.

Abubakar ni awọn fun Jẹgẹdẹ loore-ọfẹ ati ṣayẹwo awọn nnkan idibo ti wọn lo lawọn ijọba ibilẹ bii Ọwọ, Ilajẹ, Ẹsẹ-Odo, Okitipupa atawọn ibomi-in ti Akeredolu ti wọle.

Ayẹwo ọhun ni wọn lo gbọdọ waye ni olu ileesẹ ajọ eleto idibo to wa l’Akurẹ laarin aago mẹjọ aarọ si mẹrin irọlẹ ọjọ Aje, Mọnde, si ọjọ Ẹti, Furaidee.

Igbimọ ọhun tun gba ẹbẹ agbẹjọro Jẹgẹdẹ, Amofin Jamiu Makinde, to ti beere fun lilẹ iwe ipẹjọ to yẹ ko fun awọn olujẹjọ mọ oju patako to wa nile-ẹjọ wọle.

Ọsẹ to kọja ni Eyitayọ Jẹgẹdẹ mo ri le ile-ẹjọ ọhun lati pẹjọ ta ko bi wọn ajọ eleto idibo ṣe kede Gomina Rotimi Akeredolu gẹgẹ bii ẹni to yege ninu eto idibo naa.

Leave a Reply