Ile-ẹjọ tu nọọsi ti wọn lo ṣeku pa Sẹnetọ Isiaka Adeleke lọjọsi sile, wọn ni ko mọ nnkan kan nipa rẹ

Dada Ajikanje

Ile-ẹjọ giga kan nipinlẹ Ọṣun ti fidi ẹ mulẹ pe nọọsi kan, Alfred Aderibigbe, to tọju Sẹnetọ Isiaka Adeleke to jade laye lọjọ kẹtalelogun, oṣu kẹrin, ọdun 2017, ko lọwọ ninu iku to pa ọkunrin oloṣelu naa.

Ni kete ti ọkunrin oloṣelu naa jade laye ni Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, ẹni ti i ṣe gomina ipinlẹ Ọṣun nigba naa ti gbe igbimọ kan kalẹ, ninu eyi to fi Onidaajọ Oluṣẹgun Ayilara ṣe olori ẹ, lati ṣewadii iku to pa ọkunrin oloṣelu naa.

Ninu iwadii ọhun ni wọn ti fidi ẹ mulẹ pe oogun kan ti wọn fun ọkunrin ọhun lapọju pẹlu ohun to ṣeku pa a.

Ayilara yii naa lo sọ pe ọpọlọpọ oogun oorun ati oogun ara riro ti Isiaka Adeleke, lo pẹlu ohun to ṣeku pa a, ati pe imọran Alfred Aderibigbe to tẹle gan-an lo fa iku ojiji fun un.

Bakan naa ni iwadii igbimọ ọhun tun fidi ẹ mulẹ pe ọti ti ọkunrin oloṣelu yii ti mu tẹlẹ paapaa jẹ ki awọn oogun to lo yii ṣiṣẹ sodi, to si ṣokunfa bi ẹmi ẹ ṣe bọ.

ALAROYE gbọ pe lati nnkan bii ogun ọdun sẹyin ni Alfred Aderibigbe yii ti maa n ṣetọju Sẹnetọ Adeleke, gomina ipinlẹ Ọṣun tẹlẹ lai tẹle apejuwe dokita akọṣẹmọṣẹ.

Siwaju si i, Ayilara yii naa lo sọ pe ki wọn mu ọkunrin nọọsi yii daadaa, nitori ko pẹ to tọju Sẹnetọ Adeleke tan ni ọkunrin naa jade laye. Bẹẹ lo fidi ẹ mulẹ pe ọkunrin naa ko kun oju oṣunwọn to lati tọju ẹnikẹni, ati pe niṣe lo yẹ ki ijọba ba a ṣẹjọ.

Ọjọ kẹjọ, oṣu kẹfa, ọdun 2018, ni wọn wọ Alfred Aderibigbe lọ si ile-ẹjọ giga, nibẹ naa lo ti sọ pe oun ko jẹbi ẹsun apaayan ti wọn fi kan oun.

Lasiko igbẹjọ ọhun, awọn ẹlẹrii mẹsan-an ni Amofin Dapọ Adeniji, ẹni ti i ṣe akọwe agba fun ileeṣẹ eto idajọ ipinlẹ Ọṣun ko wa sile-ẹjọ, bakan naa lo tun ko awọn ohun ẹri oriṣiiriṣii wa pẹlu.

Lara awọn to wa jẹrii ta ko Aderibigbe ni ọga agba fun ileewosan Ladoke Akintọla University Teaching Hospital, niluu Osogbo, Ọjọgbọn Akeem Lasisi, ẹni to ṣayẹwo oku arakunrin naa, bakan naa ni Dokita Taiwo Sholaja, ọlọpaa to fi imọ sayẹnsi ṣeto ayẹwo lori oku naa yọju ni kootu, atawọn mi-in.

Aderibigbe sọ ni kootu pe ko si aṣilo ninu oogun ti oun fun Sẹnetọ Adeleke nigba aye rẹ, nitori odiwọn oogun to yẹ ko lo gan-an loun maa n fun un.

Lara ohun to si ko ọkunrin yii yọ ni bi agbẹjọro ẹ, Sọji Oyetayọ, ṣe sọ niwaju adajọ pe ko si eyikeyii ninu awọn ẹlẹrii yii ti wọn yọju si ile Adeleke lati mọ boya oogun ti wọn ko wa yii gan-an ni oloogbe ọhun lo nigba aye ẹ.

O ni, “Ilana ti dokita fi silẹ ni onibaara mi n tẹle lati fun Adeleke loogun, bẹẹ dokita kan lati Eko lo kọ awọn oogun ati abẹrẹ to lo fun oloogbe yii. Yoo dun mọ wa ninu ti Oluwa mi ba le da ẹjọ yii nu, ki ile-ẹjọ si tu onibaara mi silẹ.”

Nigba ti Adajọ Ayọ Oyebiyi n gbe idajọ ẹ kalẹ, o sọ pe awọn olupejọ ko ri ẹri to munadoko gbe silẹ, fun idi eyi, oun tu ọkunrin naa silẹ, ki Alfred Aderibigbe, maa lọ sile ẹ layọ.

Leave a Reply