Ile-ẹjọ yẹ aga mọ Secondus, alaga ẹgbẹ PDP, nidii

Faith Adebọla

 Ile-ẹjọ giga kan to fikalẹ siluu Port-Harcourt, nipinlẹ Rivers, ti paṣẹ pe ki alaga ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), Ọmọọba Uche Secondus, ṣi lọọ wabikan jokoo si na, ko gbọdọ pera ẹ ni alaga ẹgbẹ oṣelu PDP tabi ọmọ-ẹgbẹ oṣelu naa paapaa, titi tawọn maa fi pari igbẹjọ lori ẹsun ti wọn fi kan an nile-ẹjọ naa.

Ọsan ọjọ Aje, Mọnde, ni idajọ yii waye ninu ẹjọ kan ti awọn ọmọ ẹgbẹ PDP mẹrin, Alex Ernest Ibeawuchi, Dennis Nna Amadi, Stephen Emmanuel ati Onucha Umezurike, pe ta ko alaga ẹgbẹ wọn, Secondus, ati ẹgbẹ PDP.

Onidaajọ O. Ghassah to paṣẹ ọhun lorukọ ile-ẹjọ naa tun fi kun un pe titi tawọn maa fi pari igbẹjọ to n lọ lọwọ yii, Secondus ko gbọdọ paṣẹ tabi ṣeto idibo abẹle lati yan awọn adari ẹgbẹ bẹrẹ lati wọọdu, ijọba ibilẹ tabi ni ipinlẹ eyikeyii, bẹẹ ni ko gbọdọ lọ sipade kan lorukọ ẹgbẹ PDP, ko si gbọdọ ṣoju tabi sọrọ lorukọ ẹgbẹ naa nibikibi lasiko yii na.

Adajọ Ghassah tun paṣẹ pe ki awọn akọda kootu wa Ọmọọba Secondus lawari nibikibi to ba wa, ki wọn si fun un niwee ipẹjọ ati aṣẹ ile-ẹjọ naa, ṣugbọn ti wọn o ba ri i, ki wọn lọọ lẹ awọn iwe naa mọ geeti ile rẹ, ko le ri i ka nigbakuugba to ba fẹẹ wọle tabi jade.

Tẹ o ba gbagbe, lati bii ọsẹ meji sẹyin lawọn agbagba ẹgbẹ PDP ti ṣepade leralera latari bawọn ọmọ ẹgbẹ naa lapa kan ṣe sọ pe dandan ni ki alaga ọhun kuro nipo, wọn lawọn o fẹ bo ṣe n dari ẹgbẹ ọhun.

Ṣugbọn awọn agbaagba ẹgbẹ fẹnu ko pe ki alaga naa ṣeto ipade gbogbogboo nibi ti wọn yoo ti le yan alaga atawọn adari ẹgbẹ, o pẹ tan, ninu oṣu kẹwaa ọdun yii.

Leave a Reply