Nitori wọn kuro lẹgbẹ PDP to gbe wọn wọle, ile-ẹjọ yẹ aga nidii awọn aṣofin APC ogun ni Cross River

Faith Adebọla

Ifa kọ, ifa o fọ’re fawọn aṣofin ogun (20) to wa nipinlẹ Cross Rivers lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹta yii, ile-ẹjọ giga apapọ kan niluu Abuja ti da awọn aṣofin naa lẹbi, latari bi wọn ṣe fi ẹgbẹ oṣelu PDP ti wọn ti dibo fun silẹ, ti wọn lọọ darapọ mọ APC. Adajọ ti paṣẹ ki gbogbo wọn fipo silẹ, ki ajọ eleto idibo si ṣeto idibo mi-in laipẹ lati rọpo gbogbo wọn.

Adajọ Taiwo Taiwo lo gbe idajọ rẹ kalẹ lori ẹjọ kan ti ẹgbẹ Peoples Democratic Party (PDP) pe ta ko Gomina ipinlẹ naa, Ọgbẹni Ben Ayade, atawọn aṣofin ipinlẹ ọhun fun bi gbogbo wọn ṣe kuro lẹgbẹ PDP, ti wọn di ọmọ-ẹgbẹ APC.

Adajọ ni: “Igbesẹ tawọn aṣofin ogun yii gbe ko bofin mu, niṣe ni awijare wọn si fẹẹ ṣi ile-ẹjọ lọna.

“Iwe ẹsun ti wọn kọ ta ko ẹjọ yii ko lẹsẹ nilẹ. O lodi fun wọn lati kuro ninu ẹgbẹ ti wọn ti fibo gbe wọn dori ipo.

“Ile-ẹjọ yii paṣẹ ki wọn kuro nipo aṣofin loju-ẹsẹ, ki ajọ INEC ṣeto idibo mi-in lati rọpo wọn.”

Leave a Reply