Ile-ẹjọ yọ awọn alaga kansu mẹrẹrindinlogun nipo ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọṣẹ to kọja yii, ni ile-ẹjọ giga kan to jokoo siluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, paṣẹ yiyọ awọn alaga afun-n-sọ mẹrẹrindinlogun nipinlẹ naa nipo fẹsun pe ọna aitọ ni Gomina Abdulrazak gba yan wọn nipo.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ karun-un, oṣu kẹta, ọdun yii, ni gomina yan wọn si awọn ijọba ibilẹ mẹrẹrindinlogun to wa nipinlẹ Kwara, ti ẹgbẹ kan ti wọn n pe ara wọn ni (Trustees of the Elites Network for Sustainable Development) si wọ Abdulrazak ati agbẹjọro agba to tun jẹ kọmisanna lẹka eto idajọ nipinlẹ Kwara lọ sile-ẹjọ fẹsun pe ọna aitọ ni wọn gba yan awọn alaga naa sipo, ti wọn si n beere pe agbara wo ni Abdulrazak ni labẹ ofin lati yọ awọn alaga kansu ti wọn dibo yan kuro nipo, to si fi awọn miiran rọpo wọn.

Onidaajọ H.A. Gegele ni ko si ninu ofin kankan nilẹ yii to sọ pe gomina le yọ awọn alaga ti wọn dibo yan, ko si fi awọn mi-in rọpo lọna aitọ. Fun idi eyi, ki awọn alaga ti gomina yan lọna aitọ yii lọọ rọọkun nile.

 

Leave a Reply