Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ile-igbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo ti ni kawọn aṣofin mẹrin ti wọn da duro ni nnkan bii oṣu mẹrin sẹyin pada si aaye wọn lẹyẹ-o-ṣọka.
Igbakeji olori ile tẹlẹ, Ọnọrebu Irọju Ogundeji, olori awọn ọmọ ile to kere ju, Tọmide Akinribido, Adewinlẹ Adewale Williams to n ṣoju awọn eeyan ijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ondo kin-in-ni àti Abilekọ Favour Tomowewo lati ijọba ibilẹ Ilajẹ ni wọn da duro ninu oṣu keje, ọdun ta a wa yii, lori ẹsun ṣiṣe afojudi si ofin ile-igbimọ naa.
Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ ta a wa yii, lo yẹ ki olori ile-igbimọ ọhun, Ọnọrebu Bamidele Ọlẹyẹlogun, atawọn meji mi-in fara han nile-ẹjọ giga kan l’Akurẹ fun bi wọn ṣe kọ lati tẹle idajọ ile-ẹjọ mejeeji to pasẹ dida awọn aṣofin mẹrẹẹrin pada saaye wọn.
O ṣee ṣe ko jẹ ibẹru ẹsun siṣe afojudi si idajọ ile-ẹjọ ti wọn fẹẹ lọọ jẹjọ rẹ lo ṣokunfa bi wọn ṣe sare pe wọn pada laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.