Ilẹ mọ ba awọn janduku afẹmiṣofo, awọn ṣọja pa mọkanla ninu wọn nifọna-fọnṣu

Adewale Adeoye

Ilẹ mọ ba oloro awọn janduku afẹmiṣofo ti wọn ko jẹ ki awọn olugbe ijọba ibilẹ Birnin-Gwari, nipinlẹ Kaduna, foju loorun nitori bi wọn ṣe n ya wọn awọn ilu to wa nijọba ibilẹ naa, ti wọn si n pa awọn eeyan bii ẹni pẹran.

Lara awọn ilu keekeeke tawọn janduku naa ko ti jẹ ki awọn eeyan ibẹ rimu mi, ṣugbọn tawọn ṣọja lọọ ka wọn mọbẹ ni: Bagoma, Rema,  Gugai, Dagara, Sabon Layi, Gagumi Katakaki pẹlu Randagi.

Ọjọ gbogbo ni tole, ọjọ kan ni tolohun, lawọn ṣọja ilẹ wa fi ọrọ naa ṣe pẹlu bi wọn ṣe lọọ ka awọn olubi ẹda naa mọ ibuba wọn tijatija, ti wọn si pa mọkanla ninu wọn. Bakan naa ni wọn gba awọn ohun ija wọn bii ibọn atawọn nnkan mi-in, ti wọn si dana sun ọpọ nnkan ti wọn ba nibẹ.

Ọkan pataki lara awọn ọga agba ileeṣẹ to n ri sọrọ eto aabo abẹle nipinlẹ Kaduna, Ọgbẹni Samuel Aruwan, lo sọrọ ọhun di mimọ lakooko to n ba awọn oniroyin sọrọ nipa aṣeyọri iṣẹ tawọn ṣoja ilẹ wa ṣe laipẹ yii.

Aruwan ni tuutuu lawọn ṣoja naa fọ gbogbo aarin ilu to wa nijọba ibilẹ naa, ti wọn si koju awọn janduku agbebọn naa pẹlu ohun ija oloro ọwọ wọn.

Lara awọn ohun ti wọn ri gba lọwọ wọn ni oniruuru ibọn AK47, ọpọ ọta ibọn AK47, ibọn agbelẹrọ. Bakan naa ni wọn dana sun awọn  ọkada atawọn nnkan mi-in ti wọn ba nibẹ.

Ọgbẹni Samuel Aruwan ni lagbegbe Katakaki ni awọn ṣoja naa ti ṣiṣẹ ju lọ, nigba ti wọn koju ọpọ lara awọn janduku agbebọn naa, ti ọwọ si tẹ ọkan lara awọn olori wọn.

Leave a Reply