Ilẹ-Oluji ni Taju ti lọọ fi mọto ji ewurẹ ko tọwọ fi te ẹ

Idowu Akinrẹmi

Ṣinkun bayii ni awọn ọdọ atawọn ọlọkada agbegbe Bamikẹmọ Ọja, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ilẹ-Oluji, nipinlẹ Ondo, mu ọkunrin kan, Tajudeen Fẹmi, lasiko to n ji ewurẹ gbe ni nnkan bii aago mẹsan-an alẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹwaa.

Ki i ṣẹ Taju nikan lo wa, oun atawọn meji kan ti wọn ti sa lọ bayii ni wọn jọ gbe mọto  Nissan kan ti nọmba ẹ jẹ FGB 736 XA wa si adugbo naa, ti wọn si da ẹwa silẹ fawọn ewurẹ to wa nitosi lati maa jẹ, nigba naa ni wọn si bẹrẹ si i ko awọn ewurẹ naa sinu ọkọ.

Ere buruku ni mọto naa bẹrẹ si i sa lọ lẹyin to ji awọn ewurẹ naa tan gẹgẹ bi ẹnikan tọrọ naa ṣoju ẹ, Afeez Akindoju, ṣe ṣalaye fun ALAROYE.

Niṣe lawọn ọlọkada atawọn ọdọ gba ya wọn, ti wọn si le wọn wọnu igbo ti wọn sa wọ.

Lẹyin lile ti wọn le wọn naa lọwọ ba Taju , o si jẹwọ pe oun ti n ji ewurẹ gbe tipẹ. O ni Ile-Ifẹ ati Ilẹ-Oluji, nipinlẹ Ondo, loun ti n ṣiṣẹ ewurẹ jiji gbe naa.

Ọkunrin yii ti wa latimọle ọlọpaa Ilẹ-Oluji bayii, bẹẹ ni iṣẹ n lọ lori bi wọn yoo ṣe mu awọn meji yooku to sa lọ.

Leave a Reply