Ile ori oke kan tun da wo lu awọn to n ṣiṣẹ lọwọ ni Badagry

Jọkẹ Amọri

Iroyin to n tẹ ALAROYE lọwọ ni pe ile ori oke kan ti tun da wo ni adugbo kan ti wọn n pe ni Sunny Field, Flour Mills Estate, Magbọn, niluu Badagry, nipinlẹ Eko.

Gẹgẹ bi atẹjade to tẹ ALAROYE lọwọ lati ọdọ Ọga agba ileeṣẹ panapana nipinlẹ Eko, Abilekọ Margret Adeṣẹyẹ, o ṣalaye pe ileesẹ panapana ẹka ti Badagry ti doola ẹmi marun-un ninu awọn eeyan to wa labẹ ile naa, ti akitiyan si n lọ lati doola ẹmi awọn to ku.

O ṣalaye pe awọn oṣiṣẹ to n ṣiṣẹ nibi ile naa ni ọpọ awọn ti ile naa da wo le lori. Adeṣẹyẹ ni awọn eeyan naa ṣeṣe ni oniruuru ọna, awọn si ti gbe wọn lọ sọsibitu, nibi ti wọn ti n gba itọju lọwọ.

Awọn ọkunrin agbalagba mẹrin lo lawọn ti yọ jade, ṣugbọn awọn eeyan naa ko mọ boya aye ni awọn wa tabi ọrun. O fi kun un pe awọn ọlọpaa teṣan Morogbo atawọn araadugbo naa ti n ran ajọ panapana lọwọ lati doola awọn to ku labẹ awoku ile naa.

Leave a Reply